Ọ̀gá méjì ò lè wakọ̀ kan ṣoṣo ni mo fi yọ Auxiliary nípò – Makinde
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní bí gbogbo nnkan bá yí padà, bí n ó ṣe ṣe nnkan mi nìyí kò yí padà.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ṣàlàyé ìdí tó fi ní kí alága tẹ́lẹ̀ rí fún gááràjì ní ìpínlẹ̀ náà, Alhaji Mukaila Lamidi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Auxiliary lọ rọ́kún nílé.
Makinde ní ọba kò lè pé méjì láàfin ni òun fi fọwọ́ òsì júwe ilé fún Auxiliary.
Níbi ètò ìsìn ìdúpẹ́ fún ìbúrawọlé sáà kejì rẹ̀ ní ilé ìjọsìn Cathedral of St. Peter, Aremo, Ibadan lọ́jọ́ Àìkú ni Seyi Makinde ti sọ̀rọ̀ náà.
Makinde sọ àrídájú rẹ̀ wí pé ìjọba yóò ṣe àfọ̀mọ́ àwọn gáréèjì àti pé gbogbo àwọn tó ń da ìlú láàmú ni àwọn máa fi òfin gbé.
Ó ṣàlàyé pé kí ètò ìdìbò tó wáyé ni àwọn ti pe àwọn alókòóso gáréèjì sí ìpàdé láti ṣe ìkìlọ̀ fún wọn pé àwọn kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa fa wàhálà.
“A ṣàlàyé fún wọn pé tí a bá wọlé fún sáà kejì, a máa ri dájú pé àláfíà jọba, tí a máa ri pé ìrẹ́pọ̀ wà láàárín wọn.”
“Ẹnìkan ló fárígá pé òun kò lè bá àwọn yòókù ṣe, èmi náà sì sọ pé ìjọba méjì kò lè máa ṣàkóso ìlú kan.”