Makinde yan alága ẹgbẹ́ awakọ̀ PMS tuntun láti rọ́pò Auxiliary l’Ọ́yọ̀ọ́

Makinde yan alága ẹgbẹ́ awakọ̀ PMS tuntun láti rọ́pò Auxiliary l’Ọ́yọ̀ọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní bí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọmọ ẹranko ò bá bàjẹ́,ọmọ èèyàn ò le dùn, bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ dà báyìí, bí Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ ìṣàkóso Onímọ̀ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé ti kéde Ahaji
Oluwatomiwa Omolewa, akọ̀wé ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ tó ń se àkóso àwọn gáréèjì ọkọ̀ níìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, PMS tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alága tuntun fún ẹgbẹ́ náà níìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Bákan náà ni ìjọba Ọ̀yọ́ kéde pé Alhaji Kasali Ajisafe Lawal tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Baba Bola yóó sì jẹ́ Akọ̀wé ẹgbẹ́ tuntun.

Èyí ló jẹyọ nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ Gómìnà lórí ìròyìn, Sulamion Olarenwaju fi ránṣẹ́ sí àwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ àìkú.

Àtẹ̀jáde náà ní lẹ́yìn
tí ìjọba se ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ tó ń se àkóso àwọn gáréèjì ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, PMS ni wọ́n yan alága tuntun ọ̀hún.
Àtẹ̀jáde náà ní; “ Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń fi àsìkò yìí kéde Alhaji Oluwatomiwa Omolewa, akọ̀wé ẹgbẹ́ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alága tuntun fún ẹgbẹ́ PMS ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

“Alhaji Kasali Ajisafe Lawal tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bàbá Bola yóó sì jẹ́ akọ̀wé ẹgbẹ́ náà

“ Èyí ni àtúnṣe tí ìjọba fẹ́ se sí ẹgbẹ́ àwọn ibùdókò ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ .”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here