NLC kò yọjú,TUC, ìjọba ṣèpàdé lórí owó oṣù tó kéré jùlọ

NLC kò yọjú,TUC, ìjọba ṣèpàdé lórí owó oṣù tó kéré jùlọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba àpapọ̀ Orílẹ̀ yìí ti ní àwọn yóò ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ TUC gbé síwájú àwọn tó fi mọ́ owó oṣù tó kéré jùlọ.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé tó wáyé láàárín ìjọba àpapọ̀ àti TUC èyí tó wáyé fún bíi wákàtí mẹ́ta, Agbẹnusọ ìjọba àpapọ̀, Dele Alake ní àwọn máa wò ó tó bá jẹ́ wí pé àwọn ìbéèrè jẹ́ ohun tí ìjọba le ṣe àmúṣẹ rẹ̀.

Ó ní lára nǹkan tí ìjọba ń rò láti ṣe tẹ́lẹ̀ láti mú ìdẹ̀kùn báwọn lórí ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tí wọ́n yọ ni láti fi ojú fo owó orí fún wọn fún ìgbà kan ná.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC kọ̀ láti yọjú síbi ìpàdé náà.

Alake ní ohun tó dájú ni pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yóò gbé ìgbìmọ̀ kan dìde èyí tí àwọn ìpínlẹ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò ní aṣojú níbẹ̀, tí wọn yóò sì jíròrò lórí owó òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ.

Ó ṣàlàyé pé kò sí aáwọ̀ láàárín ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nigeria Labour Congress, NLC lórí ìbéèrè wọn pé kí ìjọba fowo kún owó òṣìṣẹ́.

Bákan náà ló fi kun pé bí NLC kò ṣe sí níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ Àìkú kò túmọ̀ sí pé wọ́n fojú kéré wọn.

Agbẹnusọ Tinubu ní ìjọba àpapọ̀ tún ti ń gbìyànjú láti kàn sí wọn fún ìpàdé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Ẹ̀wẹ̀, TUC nínú ìbéèrè tí wọ́n gbé síwájú ìjọba àpapọ̀ ní kí ìjọba dá owó epo padà sí iye tó wà tẹ́lẹ̀ kí ìjíròrò fi wáyé láàárín wọn.

Ààrẹ TUC, Festus Osifo ní àwọn ní ìrètí pé ìjọba àpapọ̀ yóò gbọ́ tàwọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣe ìlérí pàápàá lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù tó kéré jùlọ tí òṣìṣẹ́ yóò máa gbà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here