Ààrẹ Tinubu ṣèpàdé bòńkẹ́lẹ́ pẹ̀lú Wike, Makinde àti Ibori

Ààrẹ Tinubu ṣèpàdé bòńkẹ́lẹ́ pẹ̀lú Wike, Makinde àti Ibori

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní ohun tí a kò bá fẹ́ kó bàjẹ, ó ní bí wọ́n ti í se. Bẹ́ẹ̀ ohun tí a bá fi pamọ́ òhun níí níyì.
Títí di àkókò tá a sa ìròyìn yìí jọ, kò tí ì sẹ́ni tó mọ kókó ohun tí ìpàdé ìdákọ́nkọ́ kan tó wáyé láàrin olórí orílẹ̀-èdè yìí, Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers tẹlẹ, Ọgbẹni Nysom Wike, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣeyi Mákindé àti Olóyè James Ibori, èyí tó wáyé nínú ọọ́fíìsì Ààrẹ tó wà ní Aso Rock, nílùú Abùjá dá lé lórí. Ohun táwọn kan tó sún mọ́ àwọn èèyàn náà dáadáa ń sọ ni pé ìpàdé pàjáwìrì náà ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òṣèlú ilẹ̀ wa, àti pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n tún fẹ́ gba ipò pàtàkì nínú ìjọba Tinubu, nítorí pé kò fara sin rárá pé àwọn èèyàn náà kópa pàtàkì lákòókò tí ọkùnrin yìí ń dupò Ààrẹ orílẹ-èdè yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni wọ́n.

Ohun tí a gbọ́ ni pé nnkan bíí aago méjì ààbọ̀ ọ̀sàn ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejì, oṣù Kẹfà, ọdún 2023 yìí, làwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dé sílùú Abuja, bí wọ́n ti ṣe dé sílé ìjọba ní Aso Rock, ni wọ́n ti lọ tààràtà síbi tí Ààrẹ Tinubu ti n dúró dè wọ́n fún ìpàdé pàtàkì ọ̀hún.

Wọn kò gba àwọn oníròyìn kankan lààyè láti bá àwọn èèyàn ọ̀hún wọnú ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣèpàdé pàtàkì ọ̀hún pẹ̀lú Aarẹ, èyí ló si fà á ti kò fi sẹ́ni tó mọ kókó ohun tí ìpàdè bònkẹ́lẹ́ nàà dá lé lórí láàrin àwọn èèyàn ọ̀hún.

Bẹ́ẹ̀ ò bá gbàgbé, kí Wike tóó fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers ló ti ránṣẹ pe Tinubu pé kó wáá b’óun ṣí àwọn iṣẹ́ àkànṣe pàtàkì kan tí ìjọba rẹ̀ ṣe fáwọn aráàlú ní ìpínlẹ̀ rẹ̀. Ìgbésẹ̀ yìí ló mú ki ọ̀pọ̀ máa sọ pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Wike pàápàá kò ní í pẹ́ kéde pé òun ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC báyìí.

Bákan náà làwọn kọ̀ọ̀kan ń sọ pé àtìlẹ́yìn nlá ti Wike àti Gómìnà Mákindé ṣe fún Ààrẹ Tinubu wà lára ohun tó gbé e dépò ọ̀hún, nítorí pé kì í ṣe ìbò kékeré rárá làwọn méjèèjì fún Tinubu ní ìpínlẹ̀ wọn lákòókò ìbò tó wáyé lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, oṣù Kejì, ọdún 2023 yìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here