Àìlera Akérédolú fa awuyewuye ní ìpínlẹ̀ Òǹdó
Fẹ́mi Akínṣọlá
Awuyewuye ló ti bẹ́ sílẹ̀ lórí ipò ìlera Gómìnà Oluwarotimi Akeredolu ti ìpínlẹ̀ Òǹdó láti bíi wákàtí mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn.
Ìwé ìròyìn orí ẹ̀rọ̀ ayélujára kan ló ti kọ́kọ́ gbé ìròyìn pé Gómìnà Akérédolú kò lè dìde mọ́ débi pé yóó rìn kó tóó di pé púpọ̀ nínú àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí níí kọminú nípa ipò ìlera Gómìnà náà lórí ẹ̀rọ ayélujára tí àwọn kan sì ń kó ara wọn jọ ní méjì mẹ́ta láti sọọ̀ láàrin ìgboro.
Kódà àwọn kan tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí níí sọọ́ lórí ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ ‘facebook’ pé Gómìnà náà kò sí láyé mọ́, léyìí táwọn alátìlẹ́yìn Gómìnà ọ̀ún wí pé irọ́ tó jìnà pátápátá sí òótọ́ ni.
Lára ohun tó fa ìbéèrè nípa ipò ìlera Akérédolú tó ti ń ṣe Àárẹ̀ láti ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn ni bí Gómìnà náà kò ṣe yọjú síbi ayẹyẹ ibúra wọlé fún Bola Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí kò sì tún bá àwọn Gómìnà ẹgbẹ́ rẹ̀ yọjú sí Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí, Muhammadu Buhari, ní Ọjọ́bọ ọ̀sẹ̀ yìí.
Ẹgbẹ́ òṣèlú SDP ní ìpínlẹ̀ Ondo ló ti ní kí àwọn amúgbálẹ́ẹ̀gbẹ́ Gómìnà Akérédolú ò fi ipò ìlera Gómìnà náà lédè fún gbogbo ará ìlú.