NNPC ti kéde àfikún iye tí wọ́n ta jáálá èpo bẹntirol!

NNPC ti kéde àfikún iye tí wọ́n ta jáálá èpo bẹntirol!

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ilé eṣẹ epo bẹntirolu lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NNPC ti kéde àfikún owó epo bẹntirolu lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

NNPC fi léde nínú àtẹjáde tí wọ́n fi léde lójú òpó Twitter wọn láti kéde iye owó tuntun tí wọ́n ta epo báyìí.

NNPC ní bí ojú ọjà ṣe rí báyìí ló mú kí àwọn ṣe àfikún iye tí wọ́n ń ta epo báyìí.

Bákan náà ni wọ́n fikún un pé epo náà yóò wà ní yanturu fún àwọn aráàlú láti rà.

Àmọ́ wọ́n tọrọ àforíjìn lọwọ́ àwọn aráàlú tí iye owó tí wọ́n ń ta jálá epo náà lè fa ìnira fún.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò sọ oye tuntun tí wọn yóò máa ta epo náà, ṣáájú ni ìròyìn ti gbé pé epo bẹntirolu ti di ọwọn gógó báyìí lẹyìn tí àwọn iléepọ gbé owó gọbọi lé iye owó tí wọ́n ń ta jálá epo.

Ní àwọn iléepo NNPC ni wọ́n ti rí ibi tí wọ́n ti ń ta j jálá epo ní N488, tí àwọn mìíràn sì ń tà á ní N511 àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ!

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here