Ààrẹ Buhari sọ̀rọ̀ ìdágbére fún àwọn ọmọ Nàìjíría
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbàlagbà ló wí pé kò sí n tó ní ìbẹre tí kìí lópin, ere tí a dájọ́ ogún fún sísá a rẹ̀, n bọ̀ wá ku
ọ̀la .
Ìjọba Ààrẹ Buhari tó bẹrẹ pẹlú ọrọ̀ àkọkọ rẹ̀ sí àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ń lọ sí òpin diẹdiẹ pẹ̀lú ọrọ̀ ìdágbéré Ààrẹ sí aráàlú.
Lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán ni Ààrẹ ti bá àwọn aráàlú sọ̀rọ̀ ní ìgbà ìkẹhìn.
Ààrẹ Buhari yóò gbé ìjọba kalẹ̀ fún Bola Ahmed Tinubu tí aráàlú dìbò yàn.
Ayẹyẹ ìgbéjọba kalẹ̀ yí yóó wáyé lọ́jọ́ Ajé tíí ṣe ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù yí .
Ṣáájú àsìkò yí ni Ààrẹ ti bá aráàlú sọ̀rọ̀,níbi tí ó dúpẹ́ lọ́wọ́ aráàlú fún àtìlẹ́yìn ìjọba rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ló sì fi ìmoore rẹ̀ hàn ní pàápàá ádùrá aráàlú lásìkò tí ó wà nípò àìlera ní sáà rẹ̀ àkọ́kọ́.
Ààrẹ .gbóṣúbà fún ètò ìdìbò tó wáyé eléyìí tó júwe gẹ́gẹ́ bí èyí tí wọ́n fi tara tara díje rẹ̀ jùlọ nínú àkọsílẹ ìtàn ìdìbò Nàìjíríà.
Bákan náà ni Ààrẹ mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ gbígbà fún ohunkohun tí ilé-ẹjọ́ bá sọ ní pàápàá lórí ọ̀rọ̀ èsì ìdìbò tó wáyé.
Ó ní ìlànà ètò ìdìbò Nàìjíríà fààyè é lẹ̀ fún gbígba ilé ẹjọ́ lọ tí àbájáde kò bá tẹ èèyàn lọ́rùn.
Ó ní ìdí rèé táwọn tí èsì ìdìbò kò tẹ́ lọ́rùn fi lánfààní láti kọrí sílé ẹjọ́.
Àmọ́ ó ní ” bó ti lè wù ki ìdájọ́ ilé ẹjọ́ le jẹ́,mo rọ gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn láti gba ìdájọ yìí pẹ̀lú ọkàn kan, kí ẹ sì pawọ́pọ̀ láti mú àgbéga bá Naijiria”
Lábẹ́ eléyìí, ààrẹ kan sáárá sí Bola Ahmed Tinubu tí aráàlú dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.
Ó ṣàpèjúwe Tinubu gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní akitiyan tí ó sì ní ìfẹ́ ìlú lọ́kàn.
Buhari lóun ní ìgbàgbọ́ pé Tinubu yóó tẹ̀síwáju pẹlú ibi tí ìjọba òun bá ètò ìlú dé.
Ó ni Tinubu ni olùdíje tó pegedé jùlọ nínú àwọn olùdíje tó du ipò Ààrẹ.
Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí Tinubu pé ”awọn aráàlú yàn dáadáa”
Lábẹ́ ètò ààbò,Ó ní ìjọba òun gbìyànjú láti mú àdínkù bá ìwà agbésùnmọ̀mí, jàǹdùkú, adigunjalè àti àwọn ìpèníjà mìíràn.
Ààrẹ sọ pé láti lè mú kí àwọn àṣeyọrí tóun ṣe tẹ̀síwájú, ó sọ fáráàlú pé ” ẹ gbọ́dọ̀ rí pé ẹ kò sùn gbàgbéra, kí ẹ sì pawọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn agbófinró”
Lábẹ́ ìjọba Ààrẹ, ní ìpèníjà nlá ni ààbò jẹ́ tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ aráàlú sì ní ó ku díẹ̀ káàtó pẹ̀lú bí Ààrẹ kò se kojú àwọn ìpèníjà bí ajínigbé àti
agbésùnmọ̀mí .
Ó jọ pé Ààrẹ náà gba àwọn kùdìẹ̀kudiẹ yìí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú bó se ní òun ń bá àwọn òbí kẹ́dùn ọkàn lórí àwọn ”ọmọ tó wà ní iìgbèkùn” àti àwọn òbí ọrẹ àti ẹbí tí ó pàdánù ẹ̀mí àwọn èèyàn wọn nínú àwọn ìkọlù tí kò nídìí yìí.
Ààrẹ parí ọrọ̀ rẹ̀ lórí ààbò pe àwọn agbófinró ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti ríi pé wọ́n tú àwọn tó wà ní ìgbèkùn sílẹ̀ láì sí ìpalára kankan fún wọn.