Ọba méjì pàdánù ipò wọn ní ìpínlẹ̀ Kaduna
Ọrẹ Òtítọ́jù
Bó ṣe ku ọjọ́ díẹ̀ kó kúrò nípò gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Malam Nasir El-Rufai ti pàṣẹ pé kí wọ́n gba adé, ọ̀pá-àṣẹ, ìrùkẹ̀rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní i ṣe pẹ̀lú nǹkan tí wọ́n fi lè dá àwọn ọba alayé méjì kan, Ọba Jonathan Paragua Zamuna àti Ọba Aliyu Illah Yamman, tí wọ́n ń ṣàkóso lórí agbègbè Pirigi àti Arak, ní ìpínlẹ̀ náà mọ́ lọ́wọ́ wọ́n ní kíá .
Lórí ẹ̀rọ ayélujára tó jẹ́ ti Gomina Nasir El-Rufai lo ti kọkọ kede yiyọ awọn ọba mejeeji ọhun nipo fawọn araalu, ko too di pe Hajiya Umma Ahmed to jẹ Kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati fifi eeyan joye niluu naa tun fidi rẹ mulẹ, to si sọ pe yiyọ awọn ọba alaye mejeeji naa bẹrẹ lati lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.
El-Rufai kọ ọ́ sórí ẹ̀rọ ayélujára rẹ pe ‘Ijọba ipinlẹ Kaduna n fi akoko yii sọ fawọn araalu gbogbo pe Gomina Nasir El-Rufai ti bu ọwọ lu yiyọ awọn ọba alaye mejeeji yii, Ọba Jonathan Paragua Zamuna ati Ọba Aliyu Illah Yamman, ti wọn n ṣakoso lori agbegbe Pirigi ati Arak, nipinlẹ Kaduna, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii”.
Kọmiṣanna ọhun ni igbesẹ tijọba ipinlẹ naa gbe wa ni ibamu pẹlu ofin to gbe jijẹ oye ọba kalẹ nipinlẹ naa. Ti wọn si ti yan olori agbegbe Garun Karunma, Ọgbẹni Babangida Sule, ko maa dari agbegbe Piriga, titi digba ti wọn yoo fi yan olori tuntun sipo naa. Nigba ti Ọgbẹni Gomna Ahmadu to jẹ akọwe agba ilu Arak, yoo maa dari ilu Arak titi digba tijọba yoo fi yan ẹlomiran.
Ẹsun ti won fi kan wọn ni pe Ọba Illyah Yammah fi awọn oloye mẹrin kan jẹ lai jẹ pe o tẹle awọn ilana to yẹ lori ọrọ oye awọn eeyan naa. Ati pe, ki i gbe inu ilu to n ṣakoso lori rẹ rara.
Ni ti Ọba Jonathan Zamuna, ẹṣẹ toun ṣẹni pe ko mojuto akooso ilu naa rara debii pe ija igboro kan bẹ silẹ níbẹ, to si mu ọpọ ẹmi awọn araalu naa.
Wọn fi kun un pe ọba alaye naa ki i gbe inu ilu to ti jẹ ọba naa rara eyi tawọn alaṣẹ ijoba ipinlẹ naa sọ pe ki i ṣohun to daa rara.
Bẹ́ ò bá gbàgbé, àìpẹ yìí ni Gómìnà Nasir El-Rufai sọ pé ìjọba òun kò ní í yé lé àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ náà danu, àti pé títí di ọjọ́ tóun yóó lò gbẹ̀yìn nínú ìsàkóso òun lòun yóò fi máa wó àwọn ilé kọ̀ọ̀kan tí wọn kò wà ní ìbámu àti ìlànà iìkọ́lé ìpínlẹ̀ náà dànù báyìí.