Díẹ̀ ló kù kí tíá -gaàsì rán ogunlọ́gọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ sọ́run àpàpàǹdodo l’Oṣogbo

Díẹ̀ ló kù kí tíá -gaàsì rán ogunlọ́gọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ sọ́run àpàpàǹdodo l’Oṣogbo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Títí dìgbà tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, iléèwòsàn ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùndínlógójì ti Fakunle Comprehensive High School, tó wà lágbègbè Stadium, nílùú Oṣogbo, tí wọ́n forí lùgbàdì tíá-gaàsì táwọn ọlọ́pàá yìn láàárọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹtàlélọ́gbọ̀n, oṣù Karùn-ún, ọdún yìí wa.

Ohun tí a gbọ́ ni pé àwọn ọlọ́pàá kògbérèégbè Mopol 39 Base, ti àgọ́ wọn wà nítòsí ilé ẹ̀kọ́ náà ni wọ́n ń ṣeré ìdárayá aláràárọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe láti gbaradì fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì.

Níbẹ̀ ni wọ́n ti yin tíá-gaàsì sókè, ṣùgbọ́n tí afẹ́fẹ́ gbé èéfín naa lọ sínú ilé-ẹ̀kọ́ Fakunle. Báyìí làwọn akẹ́kọ̀ọ́ kọọkan bẹ̀rẹ̀ sí í húkọ́, tí àwọn mí-ìn sì dákú.

Kíákíá làwọn ọ̀gá wọn pé àwọn òṣìṣẹ́ ìtọjú pàjàwìrì, O’Ambulance, tí wọ́n sì kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ síléèwòsàn, wọ́n kó àwọn kan lọ sí ọsibítù tó wà nítòsí ilé ẹkọ́ yìí, wọ́n sì gbé àwọn kan lọ sí OSUNTHC.

Ojú-ẹsẹ̀ ni wọ́n ti pàṣẹ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù láti máa lọ sílé wọn, ṣùgbọ́n nígbà táwọn mìíràn délé ni èéfín tí wọ́n ti fà símú náà tóó fara hàn, tí wọ́n sì gbé àwọn náà lọ sọ́sibítù.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ó ní ìdárayá àràárọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe làwọn ọlọ́pàá kògbérèégbè náà ń ṣe, àti pé irú rẹ̀ kò ní í ṣẹlẹ̀ mọ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here