Afurasí ajínigbé mẹ́rin kó sí gbaga ọlọ́pàá l’Ékìtì

Afurasí ajínigbé mẹ́rin kó sí gbaga ọlọ́pàá l’Ékìtì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn tó ń yọ́lẹ̀ dà, ohun abẹ́nú á má a yọ́ wọn ṣe.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Dare Ogundare ti fojú àwọn afurasí mẹ́rìndínlógún hàn fún ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Mẹ́rin nínú àwọn afurasí yìí ni wọ́n ní àwọn nawọ́ gán ní agbègbè Òkè Ako ní ìpínlẹ̀ Ekiti àti àwọn apá ibì kan ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Ogundare tó sọ àrídájú rẹ̀ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti kò ní fi ààyè gba ìwà ọ̀daràn sọ pé, ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí ni àwọn máa gbé àwọn afurasí ọ̀hún lọ sí ilé ẹjọ́.

Ó ní àwọn ọlọ́pàá Ekiti pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kogi nawọ́ gán àwọn afurasí meji tí orúkọ won ń jẹ́ Abu Hassan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Danger àti Abubakar Sodiq.

Ó ní àwọn afurasí méjéèjì yìí ló jẹ́ ògbóǹtarigì ajínigbé tí wọ́n ń ṣọṣẹ́ ní agbègbè Iyemero/Oke-Ako/Irele/Ipao-Ekiti.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá náà ni àwọn tó ti kó sí páḿpẹ́ àwọn afurasí yìí ló dá wọn mọ̀ tí wọ́n sì nawọ́ sí wọn pé àwọn ló jí àwọn gbé.

Ó ní ìbọn tiwa-n-tiwa kan, àti ọta ni àwọn bá lọ́wọ́ wọn lásìkò tí ọwọ́ tẹ̀ wọ́n. Bákan náà ló ní ìwádìí ń tẹ̀síwájú láti ṣe àwárí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn mìíràn tó ti sá lọ.

Ó fi kun pé ọwọ́ òfin tún tẹ àwọn afurasí mìíràn, Umar Hassan àti Yusuf Lawal fẹ́sùn wí pé wọ́n yawọ agbègbè Ayenco ní Eda-Ile Ekiti tí wọ́n sì jí obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mary Olajumoke gbé.

Ó ní lẹ́yìn tí àwọn afurasí náà gba owó ìtúsílẹ̀ ni wọ́n tó tú ọmọbìnrin náà sílẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé àdá méjì àti ₦82,200 tó jẹ́ owó ìtúsílẹ̀ tí wọ́n ná kù ni àwọn bá ní ọwọ́ wọn nígbà tí ọwọ́ òfin bà wọ́n. Ó fi kun pé àwọn afurasí yòókù ni ọwọ́ bà fún ìwà ṣíṣe ẹgbẹ́ òkùnkùn àti olè jíjà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here