A ṣì ń wá ènìyàn kan nínú ilé tó dàwó lójijì – LASEMA
Fẹ́mi Akínṣọlá
À fi kí Ọlọ́run ṣá à má a pawá mọ́ nínú ewu gbogbo.
Kò dín ní ènìyàn méje tí wọ́n móríbọ́ nínú ilé tó dà wó lulẹ̀ lọ́jọ́rú ní agbègbè Banana Island, Ikoyi, ìpínlẹ̀ Eko.
Ní nǹkan bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rú ni ilé alájà méje tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ náà ṣàdédé dà wó lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́.
Ìròyìn ní pé àwọn òṣìṣẹ́ kan mórí bọ́ láì farapa, tí àwọn mìíràn sì farapa kékeré, tí àwọn mìíràn sì tún há sábẹ́ ilé náà.
Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASTMA ní àwọn ṣì ń wá ènìyàn kan tó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé ó há sábẹ́ ilé náà.
Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní orí àjà kẹfà ilé náà ní àwọn ṣiṣẹ́ dé láti gbé àjà keje le lórí kí ilé náà tó dà wó lulẹ̀.
Àtẹ̀jáde kan tí ọ̀gá àgbà àjọ LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu fi léde ní ìwádìí fi hàn pé ọkọ̀ ńlá tó ń po sìmẹ́ǹtì ló ṣokùnfà bí ilé náà ṣe dàwó.
Oke-Osanyintolu ṣàlàyé pé nígbà tí ọ̀gá ẹ̀ṣọ́ ààbò ilé náà, Anthony Onah ka àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó ku òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń wá tó sì ṣeéṣe kó ṣì wà lábẹ́ ilé ọ̀hún.
Ó ní iṣẹ́ ń lọ láti ṣàwárí ọkùnrin náà, àti pé gbogbo àwọn ohun èlò tí àwọn nílò láti fi ṣiṣẹ́ ló ti wà níbẹ̀.
Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Eko, Margaret Adeseye nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ ní ènìyàn méje ni àwọn ti yọ tó sì jẹ́ wí pé wọ́n farapa.
Adeseye ní ènìyàn kan ló ṣì wà tó há sábẹ́ ilé náà tí iṣẹ́ kò sì dúró láti yọ ẹni ọ̀hún.