Ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù yíyọ, lásìkò yìí kọ́’

‘Ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù yíyọ, lásìkò yìí kọ́’

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣéwọ́n ní èèyàn tó wẹjú lẹ̀rùn ń bà.
Àgbà agbẹjọ́rò kan, Itse Sagay ti ké sí Ààrẹ tí Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu láti jọ̀ ọ́ jàre láti wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ ètò ààbò tó ti mẹ́hẹ ní orílẹ̀ èdè yìí.

Sagay tún rọ Tinubu láti má ṣe yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tó bá dórí àléfà nítorí ìpalára tó ma kó bá àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba tó wà lóde ti ṣáájú sọ pé nínú oṣù kẹfà ọdún yìí ni àwọn yóò fi òpin sí ṣíṣe ìrànwọ́ epo bẹntiróòlù, alága ìgbìmọ̀ olùbádámọ̀ràn Ààrẹ lórí ìwà àjẹbánu náà ní òun gbàgbọ́ pé ó yẹ kí ìjọba tó ń bọ̀ ṣe ìdádúró ìgbésẹ̀ náà ná.

Ó ṣàlàyé pé nǹkan tí òun lérò pé ó yẹ kí Ààrẹ tuntun gbájúmọ́ tí wọ́n bá ti búra wọlé fún un tán ni láti mójútó ni ètò ààbò.

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí ètò kan ní Channels TV pé tí ètò ààbò bá ti dúró bó ṣe yẹ, oúnjẹ máa pọ̀ yanturu nítorí àwọn àgbẹ̀ máa lè dáko bó ṣe wù wọ́n láìsí ìbẹ̀rù.

Sagay ní lẹ́yìn èyí ni ó kan ṣíṣe àmójútó ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà àti pé yíyọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù lásìkò yìí kò ní so èso rere kan fún àwọn ènìyàn Nàìjíríà.

“Ẹnikẹ́ni tó bá ń sọ fún Tinubu pé kó yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù kàn fẹ́ ba ìṣèjọba rẹ̀ jẹ́ ni.”

Ó ní ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú títí ìjọba ma fi wá nǹkan ṣe sí àwọn ilé ìfọpo rọ̀bì Nàìjíríà.

“Tí àwọn ilé ìfọpo yìí bá ti ń ṣiṣẹ́ owó epo máa já wálẹ̀ dáadáa, ìjọba le wá ronú láti yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù nígbà náà.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here