Ìtàn ayé Seyi Makinde, gómìnà kejì tó wọlé fún sáà kejì l‘Ọ́yọ̀ ọ́

Ìtàn ayé Seyi Makinde, gómìnà kejì tó wọlé fún sáà kejì l‘Ọ́yọ̀ ọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Orí tí yóó dádé,ọrùn tí yóó lèjìgbà ìlẹ̀kẹ̀,ìbàdí tí yóó lo mọ́sàajì aṣọ ọba tí í taná yanranyanran, inú agogo idẹ ní ti í wá.
Bíntín ladáhunṣe tó mewéere, gbogbo wa lòpè nípa àkúlẹ̀yàn.
Àṣamọ̀ yìí ló fọhùn fún Gómìnà tuntun àyánrán Mákindé tí ìlú tún fìbò gbé sípò fún sáà kejì ẹni tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1967 sínú ìdílé Pà á Ọlátúbọ̀sún Mákindé àti Madam Abigail Mákindé ti agboolé Àìgbọ́fá ní Oja’ba, Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ‘Michael’s Primary School,’ Yemetu nílùú Ìbàdàn àti ‘Bishop Phillips Academy,’ Iwo Road Ibadan.

Ṣèyí Mákindé lọ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì ìpínlẹ̀ Èkó ní Akoka Yaba, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ nípa ẹ̀rọ iná mọ̀nàmọ́ná, ‘Electrical Engineering’ lọ́dún 1990.

Bákan náà ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ nípa àmójútó àwọn ilé-iṣẹ́ ńlá, ‘Industrial Control Services’ ni Houston, Texas lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1998.

Ó tún lọ sílé ẹkọ ìmọ nípa ìdàgbàsókè èsì ìṣirò, ‘Development of Analytical Competence’ ní ilé ẹ̀kọ́ fún i ìdókoòwò ní ìpínlẹ̀ Èkó (tí ó ti di Fásitì àpapọ̀ ilẹ̀ Adúláwọ̀ báyìí) lọ́dún 1999.

Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa àyẹ̀wò epo rọ̀bì ilé ẹ̀kọ́ ‘Jiskoot Auto Control Training Centre’, Kent lórílẹ̀ èdè England lọ́dún 2002.

Bákan náà ló lọ ilé ẹ̀kọ́ ìmọ nípa bí a ṣe ń yanjú àwọn ìṣòro ìdókoòwò ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ‘Massachusetts Institute of Technology,’ lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 2005.

Mákindé ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ epo rọ̀bì ‘Shell Petroleum Development Company’ fún ọdún méjì láti 1990 sí 1992 gẹ́gẹ́ bíi Onímọ̀ ẹ̀rọ.

Lẹ́yìn èyí ló ṣiṣẹ́ fún iléeṣẹ́ ‘Rebold International Limited’ gẹ́gẹ́ bíi Onímọ̀ẹ̀rọ àti igbákejì alámòójútó láàrin ọdún 1992 sí 1997.

Lọ́dún 1997 ni Mákindé bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aládàáni ti ẹ̀ gangan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní, ‘Makon Engineering and Technical Services Limited (METS) lẹ́yìn tí ó ti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀kan ò jọ̀ kan iléeṣẹ́ epo rọ̀bì fún ọdún márún un gbáko.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí iṣẹ́ àdáni rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Mákindé darapọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ òṣèlú.

Oríṣiríṣi ẹgbẹ́ òṣèlú ló darapọ̀ mọ́, kí ó tó di pé ó di ọmọ oyè fún ẹgbẹ́ òṣèlú ‘People’s Democratic Party (PDP)’ lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn án ọdún 2018.

Mákindé sì ló jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò sí ipò Gómìnà tí ó wáyé lọ́jọ́ kẹtàlélógún oṣù Kejì ọdún 2019, pẹ̀lú ònkà ìbò 515, 621.

Orúkọ aya Ṣèyí Mákindé ni Tamunominini Mákindé. Ìgbéyàwó sì ti ṣàtìwáyé àwọn ọmọ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí orúkọ wọn ń jẹ́, Fèyí, Táyọ̀ àti Tóbi.

Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, Mákindé ló borí ìbò Gómìnà tó wáyé ní ọjọ́ Sátidé, ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù kẹta ọdún 2023.

Òun sì ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Kejì tí yóò wọlé fún sáà ìkejì lẹ́yìn Abíọ́lá Ajímọ̀bi tó se sáà Kejì lórí àlééfà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ .
Ìròyìn Òwúrọ̀ kí Gómìnà kú oríire.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here