Ilẹ̀ rírì ṣọṣẹ́ ní Ecuador, èèyàn 12 kú, ọ̀pọ̀ farapa

Ilẹ̀ rírì ṣọṣẹ́ ní Ecuador, èèyàn 12 kú, ọ̀pọ̀ farapa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn tí kò tíì kú, kò tíì mọ irú ikú tí yóó pa á.
Kò dín ní ènìyàn méjìlá tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ilẹ̀ rírì tó wáyé ní ẹkùn gúúsù orílẹ̀ èdè Ecuador.

Ọ̀pọ̀ àwọn ilé ló ti dàwó ní àwọn ìlú káàkiri lẹ́yìn tí ilẹ̀ rírì tó jìn tó ìwọ̀n 6.7 magnitude èyí tó wáyé ní nǹkan bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ orílẹ̀èdè náà.

Agbègbè El Oro wà lára àwọn ìlú tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti burú jùlọ níbi tí àwọn àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní àwọn ènìyàn ṣì há sábẹ́ àwọn ilé tó dàwó.

Àwọn aláṣẹ ní El Oro ni ènìyàn mọ́kànlá ti pàdánù ẹ̀mí wọn ti ẹnìkan sì kú ní agbègbè Azuay.
Agbegbe Machala àti Cuenca náà wà lára àwọn ìlú tí ọ̀pọ̀ ilé ti dàwó, táwọn ọkọ̀ náà sì bàjẹ́ àmọ́ àwọn tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti lọ ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

Oníṣòwò kan ní Cuenca, Magaly Escandon sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn AFP pé òun sá jáde kúrò nínú ilé òun bọ́ sí ìta nígbà tí òun rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sá fi ọkọ̀ wọn sílẹ̀.

Ààrẹ Guillermo Lasso rọ àwọn ènìyàn láti ṣe sùúrù kí àwọn aláṣẹ fi mọ iye ìpalára tí ìṣẹ̀lẹ̀ ti fà.

Iléeṣẹ́ Ààrẹ ní gbogbo àwọn tó farapa nínú ìjàǹbá ọ̀hún ló ti ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn tí wọn kò sọ ohunkóhun síwájú sí i.

Wọ́n ní ọ̀pọ̀ òpópónà ni àwọn ilé ti dàwó dí ojú ọ̀nà wọn àti pé àwọn ilé ẹ̀kọ́, ilé ìwòsàn ni ìjàǹbá náà ṣe àkóbá fún.

Ilẹ̀ rírì yìí ni èyí tó fẹ́ẹ̀ lágbára jùlọ tó ń wáyé ní Ecuador lẹ́yìn èyí tó wáyé lọ́dún 2016, níbi tí ọgọ́rùn-ún méje ènìyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn tí ọ̀pọ̀ sì farapa.

Àwọn aláṣẹ ní Peru ní àwọn gbúròó ilẹ̀ rírì ní orílẹ̀ èdè ti àwọn náà àmọ́ kò sí ìròyìn bóyá ènìyàn ṣèṣe tàbí pàdánù ẹ̀mí wọn níbẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here