PDP àti APC fìjà pẹẹ́ta n‘Íbàdàn, ẹ̀mí èèyàn mẹ́ta bọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀rọ̀ àwọn àgbà ni pé, ọmọ tí yóó bá dúró sin ìyà àti bàbá rẹ̀, kìí dúró níbi ọ̀kẹ́rẹ́ bá gbé n sẹ̀.
Ènìyàn mẹ́ta ti pàdánú ẹ̀mí wọn lásìkò tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP kojú ìjà sí ara wọn níìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Agbègbè Ilé-tuntun nílùú Ìbàdàn ni ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Ìbàdàn, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé .
Gbogbo agbègbè náà ló dákẹ́ rọ́rọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní gbúùró ìbọn kíkankíkan, tí ọ̀rọ̀ sì di ẹni orí yọ, ó dilé.
Ó ṣojúùmikòró kan sọ fún àwọn oníròyìn pé àwọn mẹ́ta tó kú lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wà ní ilé ìgbóòkúsí.
Bákan náà ni wọ́n ní àsìkò tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC n ṣe ìpàdé lọ́wọ́ ní ọọ́fíìsì wọn tó wà ní Ìyànà Court, Ilé-tuntun, ní Ìbàdàn, ni àwọn alatilẹyin ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń kọjá ní agbègbè náà.
Lẹ́yìn náà ni ìjà bẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì fi ẹsùn kan ẹgbẹ òṣèlú PDP pé àwọn ni wọ́n kọ́kọ́ bẹrẹ sí ní yìnbọn fún àwọn ènìyàn àwọn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìwádìí ti bẹrẹ lórí iṣẹlẹ láti lè fi ìdí òtítọ múlẹ̀ lórí iṣẹlẹ náà, kí àlàáfíà sì jọba ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní òun pàdánù ènìyàn mẹta nínú ìjà tó bẹ sílẹ̀ láàrin ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP náà.
Wọ́n ní àwọn oní jàgídíjàgan náà ló lọ sí ilé Kánsílọ̀ kan, tí wọ́n sì yìnbọn pa á níwájú ìyàwó àti ọmọ rẹ̀.
Aṣojúṣòfin ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní Nàìjíríà tó ń ṣojú ìhà Gúúsù Ìbàdàn, Họnọrébù Abass Adigun ló fi ìdí ìṣẹlẹ náà múlẹ̀, lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀.
‘’Èmi gangan ni wọ́n fẹ́ mú balẹ̀ lásìkò tí à ń ṣe ìpolongo ìdìbò ní agbègbè Oríta Aperin sí Adesola.
Nígbà tí a dé agbègbè Ilé-Tuntun, ni a rí àwọn alátìlẹyìn ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ju omi lù wá àti òkúta.
Mo sọ fún àwọn èèyàn mi pé kí wọ́n má dà á wọn lóhùn, tí mo sì pé ọlọ́pàá ní kíákíá.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni mo rí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa lóríi kẹ̀ẹ̀kẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.
Kò pẹ́ rẹ̀ ni mo gbọ́ pé wọ́n ti pa Káńsẹ́lọ̀ ní ẹkùn mi, ní ilé rẹ̀ ní Ilé-Tuntun tí wọ́n sì pa àwọn méjì mìíràn.’’
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC, nígbà tóun náà ń ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà se wáyé ní àwọn ń ṣe ìpàdé lọwọ́ ni, olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP àti aṣójuṣòfin tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ náà wà pẹlú àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀.
Wọ́n ní aṣojúṣòfin ọ̀hún ni wọ́n rí tó sàdédé mú ìbọn, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní-ín yin ìbọn náà lu àwọn èèyàn, tí wàhálà sì bẹ́ sílẹ̀.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC náà fi ara pa yánna-yànna, tí wọ́n sì ní orí ló kó olùdíje sípò aṣòfin ìpínlẹ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC, Warris Aláwúje yọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.
Aláwújẹ sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé òun dúpẹ́ pé ẹ̀mí òun kò lọ sí iṣẹlẹ naa amọ ori lo ko oun yọ.
‘’A wà níbi ìpàdé lọ́wọ́ ni a gbọ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP n káàkiri agbègbè ọọ́fíìsì wa’’
‘’A rọ àwọn èèyàn wa pé kí wọ́n dúró, kí wọ́n lọ, àmọ́ láìpẹ́ ni ìlúmọ̀ọ́ká kan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ọ̀hún sọ̀rọ̀ wúyẹ́ wúyé sí àwọn alátìlẹyìn rẹ̀.
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní yìnbọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ara pa, tí wọ́n sì ba àwọn ọkọ̀ jẹ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.’’