CHRISTOPHER KOLADE: Onínú funfun bí ahá ẹmu

Alagba Christopher Kolade

Akeem Lasisi

Aja to ba lo si ile ekun to bo, o ye ki a ki aja ku ewu, ka si ki ekun naa ku ewu.

Ti a ba wo bi iwa ojelu ati ibaluje miiran se tan kale ni orile ede yii, ti a ba wa ri eni kan to si le we to yan kaninkanin, ti ko je ki awon jegudujera o ta epo si aso ala oun, o ye ki a kan saara si i gidi.

Eni ti a n soro nipa re naa ni Dokita Christopher Kolade, onimo, oloye to si ni mimo, oninu funfun gege bii aha emu.

Pelu ogo Olorun, Alagba Kolade lo ti di eni aadorun-un odun bayii.

Opolopo eniyan, to fi mo Aare Muhamadu Buhari, lo si n ki i ku oriire.

Won n so nipa iwa  rere re, ati idagbasoke to ti mu ba Naijiria.

Dokita Kolade je amuyangan omo Yoruba to je pe iwa omoluwabi je e logun.

Gbogbo ibi to ba wa, ko le daa lo maa n se.

Alagba Kolade

Apeere eyi ni ipo to di mu lasiko ijoba Goodluck JonathanWon fi Kolade se olori ajo ti o nawo ti won ri lori ayokuro owo iranwo lori epo (subsidy), ti a mo oruko re si SURE P.

Owo naa po tabua. To ba je pe awon eniyan miiran ni, won ko ba teba ti i ni, ti won ko ba gbogbo re da sinu apo tiwon.

Awon kan fe gbowo kowo, sugbon Kolade si ja fitafita. Nigba to ri i pe esuke fe wo rara, o ba kowe fi ipo sile.

Iru eyi kii saaba maa n waye ni orileede yii tori ohun ti awon eniyan yoo je ni won mo.

Odun 1932 ni a bi Dokita Christopher Kolade to je omo bibi ilu Erin Osun.

O lo si ile iwe Government College, Ibadan ati Foura Bay College, ni Freetown, ni Orile Ede Sierra Leone.

O ti figba kan je oga agba ni ile ise Broadcasting Corporation of Nigeria ati Cadbury Nigeria Plc.

Ni pataki, Dokita Kolade ti je ambasado fun Naijiria ni orile ede United Kingdom.

Ibi to si wa dagba de yii, Kolade si n fi ogbon ati imo boa won eniyan, nipa sise ise oluko ni Trans Atlantic Unuversity, ni Ipinle Eko.

Pelu iyi ati eye ni IROYIN OWURO se yan Dokita Kolade ni OPOMULERO YORUBA.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here