CBN pàṣẹ: Ẹ máa ná gbogbo owó àtijọ́ àti tuntun lọ títí dìparí ọdún yìí.

Nigeria's Central Bank new governor Godwin Emefiele speaks during a media briefing to announce his monetary policy in Abuja on June 5, 2014. AFP PHOTO/STRINGER (Photo by STR / AFP) (Photo by STR/AFP via Getty Images)

CBN pàṣẹ: Ẹ máa ná gbogbo owó àtijọ́ àti tuntun lọ títí dìparí ọdún yìí.

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í fojú hàn báyìí pé awuyewuye àti ìpọ́njú táwọn ọmọ orílẹ-èdè yìí ti ń kojú rẹ̀ láti ọsẹ díẹ̀ sẹ́yìn látàrí ọwọ́n gógó owó Náírà, yóò ròkun ìgbàgbé báyìí pẹ̀lú bí báńkì àpapọ ilẹ̀ wa, Central Bank of Nigeria (CBN), ṣe kéde pé àwọn fara mọ́ àṣẹ tile-ẹjọ tó ga jù lọ nilẹ wa pa láìpẹ́ yìí pé níná ni gbogbo owó,
káwọn èèyàn máa ná owó àtijọ́ àti tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rẹ láró lọ títí dìparí ọdún yìí.

Nitori eyi, CBN ti paṣẹ fawọn banki gbogbo lorileede yii pe ki wọn bẹrẹ si i gba atowo tuntun, atowo atijọ wọle, ki wọn si maa san an fawọn onibaara wọn, bẹẹ ni wọn tun rọ araalu pe ko si aṣadanu ninu awọn owo naa, ko seyii ti ki i ṣe nina, ki wọn maa na an falala bo ṣe wu wọn.

Esi ayọ yii lo wa ninu atẹjade kan ti ọba awọn banki nilẹ wa ọhun, fi lede nirọlẹ ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii, eyi ti adele fun Alakooso eto ibanisọrọ fun banki naa, Ọgbẹni Isa Abdulmumin, buwọ lu lorukọ ọga agba patapata fun banki apapọ ilẹ wa, Ọgbẹni Godwin Emefiele.

Atẹjade naa ka pe: “Niwọn bo ti di aṣa wa lati maa tẹle aṣẹ tile-ẹjọ ba pa, ka le tubọ fi idi ofin mulẹ, nibaamu pẹlu eto iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari, ati pẹlu ilana iṣẹ Central Bank of Nigeria, CBN, gẹgẹ bii banki to n dari awọn banki olokoowo gbogbo to wa ni Naijiria, a ti fun yin laṣẹ lati tẹle idajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ ti wọn gbe kalẹ lọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.

“Nitori eyi, a ti ṣepade pẹlu awọn igbimọ alakooso awọn banki gbogbo, a si ti paṣẹ fun wọn pe igba Naira (N200) atijọ, ẹẹdẹgbẹta Naira (N500) atijọ, ati ẹgbẹrun kan Naira (N1,000) atijọ ṣi jẹ owo to ṣetẹwọgba, ẹ maa na an pẹlu awọn owo Naira tuntun ta a ko boode bii ọmọ ọjọ mẹjọ laipẹ yii, titi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii.

“Kí gbogbo àwọn tọ́rọ̀ yìí kàn tara ṣàṣà láti tẹ̀lé àṣẹ yìí láì sọsẹ̀.”

Ẹ O ranti pe ọjọ kẹta, oṣu Kẹta yii, ni ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa gbe idajọ kalẹ ninu ẹjọ kan tawọn ipinlẹ bii mẹtala pe ta ko ijọba apapọ lori awuyewuye owo naira tuntun ati gbedeke tijọba apapọ ati banki apapọ fi lede. Ile-ẹjọ naa sọ ninu idajọ wọn pe gbedeke tijọba fi lelẹ naa ko tọna, o n m’ara ni araalu, ko si yẹ bẹẹ, wọn lawọn wọgi le e loju-ẹsẹ. Bakan naa ni wọn tun paṣẹ pe karaalu maa na awọn owo naa lọ, ibaa jẹ tatijọ tabi tuntun, titi di ipari ọdun yii.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here