Àdánù ńlá ni ọba tó wàjà yìí jẹ́ fún ilẹ̀ Ìjẹ̀bú lá pa pọ̀—Dapọ Abiọdun
Fẹ́mi Akínṣọlá
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti kẹdun pẹ̀lú àwọn èèyàn ilẹ̀ Idowa, àti gbogbo ilẹ̀ Ìjẹ̀bú lápapọ̀, lórí ipapoda Ọba Yinusa Ọladele Adekọya, Dagburewe tìlú Idọwa, èyí tó ṣẹlẹ̀ lalẹ ọjọ Àìkú, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹta, ọdún 2023 yìí. Abiọdun ní àlàfo tí ikú bàbá náà ṣí sílẹ̀ yóó pẹ káwọn tóó lè díi .
Nínú ọrọ̀ ibanikẹdun kan tí Gómìnà fi léde lójú òpó ayélujára rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù yìí, Dapọ Abiọdun ní: “Pẹlu ìmọ̀lára àdánù ńlá, a ń ṣọ̀fọ ipapoda àyànfẹ orí-adé tó jẹ́ bàbá wa, Alayeluwa, Ọba Yinusa Ọladele Adekọya, Dagburewe tìlú Idọwa.
“Ìṣṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ tó ká mi lára gidi lèyí jẹ́, torí àjọṣe tó dán mọ́rán, tó sì lágbára, ló wà láàrin èmi àti ọba alayé yìí, ipa ribiribi tí wọ́n sà láti mú ìgbé ayé àwọn èèyàn dára sí i kò ṣe é kóyán rẹ̀ kéré rárá, papàá jù lọ, ní Idọwa àti ilẹ̀ Ijẹbu lápapọ̀.
“A bá àwọn mọ̀lẹ́bí àtẹ̀yin èèyàn dáadáa tẹ́ ẹ wà nílùú Idọwa kẹ́dùn o, a sì ṣàdúrà pé k’Ọ́lọ́run rọ̀ yín lọ́kàn, kẹ́ ẹ lè mú àdánù tí kò látùúnṣe bíi èyí mọ́ra.”
Ọ̀rọ̀ ọ̀hún kò yàtọ̀ lọ́dọ̀ Ọtunba Gbenga Daniel, gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun tẹ́lẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn sípò sẹ́nétọ̀ lọ́sẹ̀ méjì sẹ́yìn.
Daniẹl, nínú ọrọ tirẹ, ṣọ pé: “O bà mí nínú jẹ́ gidi nígbà tí mo gbọ́ pé Dagburewe ti wàjà. Lóòótọ́ ni wọ́n fọwọ́ pawu, tí wọ́n sì fèrìgì jobì, síbẹ̀ ohun tó ṣì wù wá ni pé kí wọ́n ṣì wà pẹlú wa. A máa ṣàárò ipa rere tí wọ́n kó nínú ìfọmọnìyàn ṣe, àti fún ìdàgbàsókè ilẹ̀ Ìjẹ̀bú lápapọ̀. Mo kẹ́dùn pẹ̀lú Awùjalẹ̀ ilẹ̀ Ìjjẹ̀bú, Ọba Sikiru Káyọ̀dé Adétọ̀nà, mo sì ṣe ládùúà pé kí Ọlọ́run Olódùmarè fún ìdílé Ọba Adékọ̀yà, àti gbogbo èèyàn ìlú Idọwa ni oore-ọ̀fẹ́ láti fara da àdánù yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni Daniẹl sọ.
Látìgbà tí wọ́n ti kéde pé ọba alayé náà wàjà lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún làwọn èèyàn nlá nlá nílẹ̀ Ìjjẹ̀bú, àti ní ìpínlẹ̀ Ògùn ti n ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn, tí wọ́n sì n ròyìn ọba alayé ọ̀hún gẹ́gẹ́ bíi ọba rere, oníwà pẹ̀lẹ́, tó sì fẹ́ràn àwọn aráàlú ẹ̀, àti ilẹ̀ ẹ Yorùbá lápapọ̀.