A nílò láti gbárùkù ti àwo̩n ò̩dó̩ nítorí àwo̩n ìran tó ń bò̩ — Seyi Law

A nílò láti gbárùkù ti àwo̩n ò̩dó̩ nítorí àwo̩n ìran tó ń bò̩ — Seyi Law

Mary Fágbohùn

Aderinposonu ati osere tiata, Seyi Law, ti so pe fun awon oluadanilaraya pe lati je eni pataki sibe lawujo, won gbodo satileyin fun awon iran to n bo leyin won.

O so fun Sunday Scoop pe, “Lati je pataki sibe, eniyan nilo lati setan fun titi awon odo ti o n bo leyin. Ati pe, eniyan ko gbodo tiju lati ko lati odo enikan.”

Nigba to n soro lori eko to ti ko lenu ise re, o wi pe, “Okan lara awon eko ti mo ko ni pe awon omo Naijiria ro pe ise takuntakun eniyan ko ni fise ki eniyan to se aseyori.
Won ro pe awon ni o so eniyan di alaseyori. Sugbon, mo ti ri iro to wa ninu oro naa ti pe. Awon to n satileyin fun mi ni tooto, titi lai ni mo n dupe lowo yin, mi o le e se alaika atileyin yin si.

“Mo tun ti ko pe lara ipenija awon oludaraya ni dida irawo. Eniyan yoo se aseyori ti won ba mo o ati pe anfaani pupo yoo si sile fun.”

Aderinposonu naa tun tenumo pe awon onifonran ko ti gba ipo lowo diderinposonu aladuro se. O wi pe, “Bi awon onifonran ba ti gba ile-ise naa, ki lode ti awon naa fi n seto are diderinposonu? Ipo diderinposonu aladurose si wa nibi to wa. Diderinposonu onisisentele lo bi ti aladurose eyi to ti wa da ‘fonran sise’. Fonran sise beere pelu eniyan bi emi, AY ati Basketmouth. Ni opolopo odun seyin, mo se fonran kan ti mo pe akole re ni, Flat Tummy Jesus, gbogbo eniyan lo tewo gba a. Ti e ba wo awon fonran ode-oni, e o rerin gidi. Mo tun ti ko fonran fun die lara awon ilumooka onifonran to wa nita. Mo ti kopa ninu fonran pelu die lara won ri.”

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here