Boko Haram pa apẹja ọgbọ̀n, “UN” figbe ta

Boko Haram pa apẹja ọgbọ̀n, “UN” figbe ta

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ iṣọkan àgbáyé, UN, ti bu ẹnu àtẹ lu bí ìkọ alakatakiti ẹsìn, Boko Haram ṣe pa ó kéré tán, ọgbọ̀n èèyàn ní ìpínlẹ̀ Borno.

Apẹja làwọn èèyàn náà tí wọ́n pàdé ikú òjijì ní ìjọba ìbílẹ̀ Gamborun Ngala, níbi tí púpọ̀ nínú àwọn olùgbé rẹ̀ jẹ́ apẹja àti àgbẹ̀.

Ẹbá ìlú Mukdolo, níbi tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Boko haram pọ̀ sí ni ìkọlù ọ̀hún ti ṣẹ̀.

Ìròyìn ní àsìkò tí àwọn olóògbé ọ̀hún n lọ wá oúnjẹ òòjọ́ wọn ni Boko Haram, tí wọ́n jẹ́ ti ìhà ISWAP dẹ́mì-ín in lójijì.
Ohun a gbọ́ ní pé àwọn agbébọn náà ti ránṣẹ́ sí àwọn èèyàn ọhún ṣaájú ìkọlù, pé kí wọ́n yẹ̀bá fún agbègbè ibi tí ìṣẹlẹ ọhún ti wáyé.

Ẹnìkan tó yọjú síbi ètò sìnkú àwọn olóògbé náà ṣàlàyé fún akọ̀ròyìn pé inú ìpòrúùru ọkàn làwọn olùgbé ìlú náà ń gbé báyìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here