Mi ò gbowó ló̩wó̩ olùdíje kankan láti polongo ìbò – Toyin Abraham

Mi ò gbowó ló̩wó̩ olùdíje kankan láti polongo ìbò – Toyin Abraham

Mary Fágbohùn

Osere Nollywood, Toyin Abraham ti safihan pe atileyin oun fun oludije fun ipo aare ninu egbe oselu All Progressives Congress (APC), Bola Tinubu, kii se nitori owo.

E seranti pe osere tiata naa gba opolopo isorolodisi lori ayelujara nitori pe o kede atileyin re fun inubu.

O wi pe,“ Mo nife Asiwaju ati pe mo n soro nipa ara mi. Mo nife re. Maa dibo fun nitori pe mo nife re. Bo ti le je pe, mi o ti sepinnu, mo kan n so fun yin ni. Nitori pe o ti se opolopo nnkan fun mi ni ile-ise yi”

Lori ayelujara , yiyan oludije ti Toyin fe ti fa opolopo igboriyin ati idalebi fun n.

Toyin kolu awon omo Naijiria fun titako atileyin re fun Tinubu ninu iforojomitoro oro kan pelu Kemi Afolabi lori Instagram.

O wi pe otito ibe ni pe oun ko gbowo lowo oludije fun ipo aare ninu egbe oselu APC, awon ti won n sepe fun oun kan n fi akoko won sofo ni.

Toyin tesiwaju lati sekilo fun awon omo Naijiria pe ki jawo ninu pe a n hale mo ara wa lori ayelujara nitori oludije ti oun yan.

O wi pe, “Bi enikeni ba bumi tabi sepe fun mi, ko le ran mi nitori pe mi o gbowo. Awon to gbowo nikan ni epe le e ja.

“Emi, Oluwatoyin, mi o gbowo lowo enikeni bee si ni mi o polongo fun enikeni sugbon a n so oro yii nitori pe orile-ede mi niyi. Mo je omo Naijiria, mo si bi omo mi sibi.

“Ko seni ti le e sanwo fun mi. Mo n pawo owo wole, mo n tan fiimu mi ni sinima, mo n ta won ni awon oju awe kan, Mo n mowo wole mo si n se daadaa. Koko ni pe ki e yan oludije ti yin, e ma hale mo mi.”

 

 

 

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here