Oníjìbìtì kan rí è̩wò̩n o̩dún méjì he fún síse àfarawé òsèré tíátà Bó̩láńlé Nínálowó

Oníjìbìtì kan rí è̩wò̩n o̩dún méjì he fún síse àfarawé òsèré tíátà Bó̩láńlé Nínálowó

Mary Fàgbohùn

Onijibiti kan, Omoghan Igbinosa ti ri ewon odun meji he fun sise afarawe osere Nollywood, Bolanle Ninalowo.

Eyi ni ajo to n ri si oro magamago owo (EFCC) fi lede ni oju opo Twitter won lojo Aje.

Adajo Okon Abang ti ile ejo giga ti ijoba apapo ni Warri, ipinle Delta, se idajo re ni ojo keta-din-ni-ogun osu keji, 2023.

Esun naa ka bayii pe, “Iwo, Omoghan Destiny Igbinosa nigbakan laarin odun 2021 si 2022 ni ilu Benin, ipinle Edo laarin sakaani ile-ejo olola yii hu iwa jibiti nipa sise afarawe idanimo Ninalowo Bolanle, osere tiata Nollywood nipa fifi awon iwe kan ranse si Newon Quanon lati ori ayelujara ni eyi ti iwe ti o fi ranse naa ti so pe o wa lati odo Ninalowo Bolanle pelu erongba lati ri ere fun ara re.

“Nipase eyi lo fi se si ofin abala ikeji-le-ni-ogun ipa keji (Section 22 (2) (b) (i) Cybercrime (Prohibition Prevention,etc. Act 2015) ti ifiyajeni re si wa labe Section 22 (2) (b) (IV) abala ofin naa.

“Lori ejo yii, olujejo naa wi pe oun jebi oro naa. Nitori ebe won, olufesunkan, I. M. rawo ebe si ile-ejo lati se idajo naa boseye.

“Agbejoro olujejo, A. J. Onwuanaje ati Dickson Egberume rawo ebe si ile-ejo pe ki won je ki aanu sogo lori idajo, wi pe olujejo naa ti mo ese re lese.

“Adajo Abang se idajo fun olujejo naa o si so si ewon odun meji tabi ki o san owo itanran ti o to milionu kan naira. Olujejo naa tun gbodo padanu owo ti o to arun-din-ni-oji le ni egbeokanla owo dola ero ibanisoro re si apo ijoba apapo Naijiria.

 

 

 

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here