Káhàsà! Ọmọ Ṣani Abacha kú lójijì, wọ́n ló sùn ni ò jí mọ́

Káhàsà! Ọmọ Ṣani Abacha kú lójijì, wọ́n ló sùn ni ò jí mọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àrùn la rí wò,a ò rí ti ọlọ́jọ́ ṣe.Títí di àsìkò yìí ni àwọn èèyàn ṣì ń bá mọ̀lẹ́bí olórí orílẹ̀-èdè wa tẹ́lẹ̀, Ibrahim Sani Abacha, kẹ́dùn. Èyí kò sẹ̀yìn bí ọkàn nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe fò sánlẹ , tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ kú lójijì.

Oun tí á gbọ́ ni pé Abdullahi Abacha yìí ti ojú oorun dé ojú ikú ni nílé rẹ̀ tó wà ní òpópónà Nelson Mandella, nílùú Àbùjá. Wọ́n ní kò sí ohun tó ṣe é kó tó wọlé sùn lálẹ́ ọjọ́ náà, bẹẹ ni kì i ṣe pé àìsàn kankan ti wa lára rẹ̀ ṣaájú àsìkò tí ikú mú un lọ yìí, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn mọlẹbi ṣe sọ, ó kàn sùn náà ni, nígbà tó sì di òwurọ̀ ọjọ́ kejì ni wọ́n rí i pé ó ti sọdá sódìkejì ayé. A gbọ́ pé ọmọkùnrin ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì yìí ló wà ní ipò kẹjọ nínú àwọn ọmọ mẹ́sàn-án tí Olóògbé Sanni Abacha fi sáyé lọ.

Ẹ̀gbọ́n olóògbé náà, Fatimah-Gumsu Abacha-Buni tó jẹ́ ìyàwó Gómìnà ìpínlẹ̀ Yobe, ló kéde ọ̀rọ̀ náà lórí ìkànnì abẹ́yẹfò (twitter) rẹ̀ pé, ‘‘Inna lillahi wa inna ilaehi rajiun (Ohun tó dájú ni pé ọ̀dọ̀ Allah ni a ti wá, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ náà ni a ó padà sí). Mo pàdánù àbúrò mi, Abdullahi Sani Abacha. Ojú oorun ló ti dé ojú ikú. Kí Ọlọrun Allah fojú pa àṣìṣe rẹ̀ , kó sì tẹ ẹ sí Aljanah onídẹ̀ra. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ bá mi rántí rẹ̀ nínú ádùrá.
Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta, Sátidé, ọjọ́ kẹrin, oṣù yìí, ni wọ́n ni ètò ìsìnkú rẹ̀ yóò wáyé ní mọṣalaṣi ńlá tó wà nílùú Àbùjá láago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here