Ojúbọ̀rọ̀ kò ṣe é gbọmọ lọ́wọ́ èkùọ́ ọ wọn-Tinubu

Ojúbọ̀rọ̀ kò ṣe é gbọmọ lọ́wọ́ èkùọ́ ọ wọn-Tinubu

Ọrẹ Òtítọ́jù

Olùdíje fúnpò Ààrẹ Orílẹ̀ yìí lábẹ́ àṣìá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, Aṣíwájú Bọla Hammed Tinubu, ti sọ pé kò sí ìdíwọ́ kankan tí ẹnikẹ́ni lè ṣètó rẹ̀ tó lè dí èròngbà òun láti di Ààrẹ orílẹ̀èdè yìí lọ́wọ́.

Níbi ètò ìpolongo ìbò rẹ̀ tó waye ni Nelson Mandela Freedom Park, nílùú Òṣogbo, ló ti sọrọ yii l’Ọ́jọ́rùú, ọjọ́ keji, oṣu Keji, ọdun yii. Tinubu ni koda bi wọn sọ owo Naira di kọbọ, oun yoo wọle ibo naa.

Tinubu, ẹni ti awọn minisita, awọn gomina atawọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC lorileede yii ba kọwọọrin sọ pe awọn araalu ti ṣetan lati fẹsẹ rin lọ sibudo idibo lati dibo fun ẹgbẹ oṣelu APC.

O ní, “Ojúbọ̀rọ̀ kọ́ la fi n gba ọmọ lọwọ ekurọ. A ki i ṣe ọmọ ale. Awa la fi wọn sibẹ, awa naa la maa rọpo wọn, a maa dibo, a maa wọle.

“Kò sí nǹkan tí wọ́n lè ṣe, koda, bi wọn sọ owo Naira di kọbọ, ibi ti a ti maa dibo ko jinna silee wa, a maa fẹsẹ rin lọ sibẹ, ibikibi to wu ki wọn gbe apoti idibo si, a maa debẹ.

“Bí ẹ bá sọ pé ẹ má a mú nǹkan sú wa, a ti rin jinna, a maa duro pẹlu ipinnu ọkàn lábẹ́ ẹ bó ti wù kó rí. Gbogbo ẹyin ọdọ ti ẹ n wa iṣẹ lẹ maa riṣẹ, a maa da oriṣiiriṣii ileeṣẹ silẹ fawọn ọmọ wa.

“Ẹ̀yin tí ẹ wà nílé ẹ̀kọ́, ẹ pè mí lọ́mọ àlè tí ẹ bà lò ju ọdún mẹ́rin lọ lẹ́nu ẹ̀kọ́ ọ yín, a maa sanwo ileewe yin, a si maa ya yin lowo lati fi ṣiṣẹ”.

Tinubu tún fi àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà lọ́kàn balẹ̀ nipinlẹ Ọṣun, o ni didun lọsan yoo so fun wọn nitori ẹrin àríngbẹ̀yìn lo maa ń ni ayọ̀ nínú.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here