Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ní san owó náírà tuntun kíá lórí káúntà – Báńkì àpapọ̀ pàṣẹ!
Ọrẹ Òtítọ́jù
Ṣé wọ́n ní tí ẹ̀gún bá débi hùn, ó fẹ́ yọ ni.
Báńkì àpapọ̀ orílẹ̀èdè yìí ti sọ ọ̀rọ̀ àṣẹ jáde sí gbogbo àwọn ilé ìfowópamọ́ tó kù pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní-ín fi náírà tuntun san owó fún àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú báńkì, lòdì sí àṣẹ tí wọ́n pa ṣáájú pe ẹnu ẹ̀rọ ATM nìkan ni kí wọ́n kó owó náírà tuntun sí.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí olùdarí ẹ̀ka ibanisọ̀rọ̀ fọwọ́ si, gomina báńkì naa, Ọgbẹni Godwin Emefiele fi àṣẹ ránṣẹ́ sí awọn ile ìfowópamọ́ lati bẹ̀rẹ̀ si ni san àwọn owo tuntun ninu báńkì amọ o tun fi gbedeke ẹgbẹrun lọ́nà ogún lóòjọ́ lé e.
Wọ́n ni eléyìí ṣe pàtàkì nitori iya to n jẹ awọn ọmọ Nàìjíríà to n to sori ila gigun niwaju ẹ̀rọ ATM jakejado Nàìjíríà.
Emefiele ni awọn n ṣiṣẹ́ pọ pẹlu awọn Ileeṣẹ míì lati fi awọn to n ta owo ti wọn si n lo o nilokulo jofin paapaa àwọn to n fọn owo naa kiri ninu afẹ́fẹ́ ti wọn si n fi ẹsẹ tẹ ẹ mọ́lẹ̀ ni ode ijó.
Bakan naa lo mẹ́nu ba àṣà to gbode kan bayi pe ki wọn maa dede ko owo ti wọn ba gba ni báńkì pamọ ati pe awọn kan ti kii ṣe oṣiṣẹ báńkì kankan n ṣe pasiparọ owo naa fun awọn eeyan lórúkọ báńkì àpapọ̀.
Gbogbo èyí ni Ọ̀ga báńkì naa ni iwa ọ̀daràn gbaa ni to si lodi si abala ofin ile ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà ti ọdun 2007.
Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ òfin “ma gbe owo rin gẹlẹ bi wọn ṣe gbe awọn owo tuntun naa sita lati se ayipada igba, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ati ẹgbẹ̀rún kan náírà ti atijọ.
Ẹ̀wẹ̀, igbesẹ tuntun yii ti fi oju awọn ọmọ Nàìjíríà ri mabo lẹnu akoko ranpẹ to waye.
Lẹ́yìn ọjọ́ Kẹwàá Oṣù Kejì, gbogbo owo náírà atijọ ni yoo di afisẹyin bi eegun ṣe n fi aṣọ ni Nàìjíríà eyi tumọ si wi pe ẹnikẹni ko le e ni anfani lati na awọn owo naa mọ lati fi ra tabi ta nkankan.