Àtubọ̀tán ayé! Idris fipá bá ẹlẹ́hàá lò pọ̀ nínú mọ́ṣálásí, kan n‘Íbàdàn

Àtubọ̀tán ayé! Idris fipá bá ẹlẹ́hàá lò pọ̀ nínú mọ́ṣálásí, kan n‘Íbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Wọ́n ní tọ́ ọmọ ọ̀ rẹ sí ìlànà Ọlọ́run, kó má dà
gbà ya gànálugi.
Àwọn ẹgbẹ́ Mùsùlùmí lóríṣìíríṣìí ni wọ́n tú jáde lọ́jọ́ Ajé, ọgbọ̀ńjọ́, oṣù Kín-ín-ní, ọdún yìí láti fẹ̀hònù hàn nílùú Ìbàdàn, níìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ látàrí bí ọmọkùnrin kan tí wọ́n porúkọ rẹ̀ ní Idris, ṣùgbọ́n tí àlàjẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ Késárì ṣe wọnú Mọ́ṣálásí kan lọ ní agbègbè Iwo Road, tó sì lọ̀ ọ́ fipá bá ẹlẹ́hàá tó wà nínú Mọ́ṣálásí ọ̀hún sun-un-run kòtọ́ lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kín-ín-ní, ọdún yìí.

Ọmọ ọ̀kan nínú àwọn onímọ́tò ni wọ́n pe ọmọkùnrin tó yọ́ wọnú mọ́ṣáláṣí ọ̀hún, tó sì fipá bá obìnrin tó wà nínú aṣọ ẹ̀há lò pọ̀.

Ìbínú ọ̀rọ̀ yìí ni àwọn àgbààgbà ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí nílùú Ìbàdàn, èyí tí gbajúmọ̀ oníwáàsí n-nì, Sheik Amúbíẹyá, darí ṣe fi ẹ̀hónú hàn ta ko ìwà ìtàbùkù sí ọmọlúàbí ọ̀hún .

Ìròyìn Òwúrọ̀ gbọ́ pé ọmọ bíbí inú ọ̀kan lára àwọn adarí ẹgbẹ́ onímọ́tò tí wọ́n ń pè ní Al-Majiri ni Idris. Ọwọ́ àwọn agbófinrí ti tẹ ọmọkùnrin ọ̀hún tó hùwà a kòtọ́ yìí, wọ́n sì ti mú un lọ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àwọn ọlọ́pàá, níbi tí wọ́n ti ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò.

Ohun tí àwọn ẹgbẹ́ Mùsùlùmí ọ̀hún ń bèèrè fún ni pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ láì jìyà. Kí wọ́n fìyà tó tọ́ jẹ ẹ́ kó lè jẹ́ ẹ̀kọ́ fún àwọn tó bá tún ní-in lọ́kàn láti dánrú ẹ̀ wò.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here