Ẹlẹwọn mẹrinla gba ominira nipinlẹ Ogun.

Ẹlẹwọn mẹrinla gba ominira nipinlẹ Ogun.

 

Lati ọwọọ Adefunkẹ Adebiyi

 

Mẹrinla ninu awọn ẹlẹwọn ti wọn kaakiri ipinlẹ Ogun ni wọn gba ominira kuro lahaamọ lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kin-in-ni ọdun 2023. Adajọ agba nipinlẹ Ogun, Mosunmọla Arinọla Dipẹolu lo sọ wọn di ominira pẹlu alaye pe ki wọn maa lọ ṣugbọn ki wọn ma dẹṣẹ mọ.

Ọgba ẹwọn Ọ̀bà, Ibara ateyi ti wọn n pe ni Borstal to wa l’Abẹokuta lawọn ẹlewọn naa ti gba itusilẹ, pẹlu eyi to wa n’Ijẹbu-Ode ti i ṣe ikẹrin wọn.

Adajọ agba Dipẹolu paṣẹ itusilẹ naa lasiko ti wọn n ṣeto kan to ni i ṣe pẹlu bi ọgba ẹwọn ṣe n kun akunfaya, eyi to waye ninu ọgba ile-ẹjọ nla ti wọn n pe ni Judiciary Complex to wa niluu Abẹokuta.

Awọn ẹlẹwọn to gba itusilẹ yii ti wa nibẹ lati ọdun 2015,2016 ati 2017. Awọn mi-in kan ṣaa wa nibẹ ni, wọn ko ti i foju ba ile-ẹjọ, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ bi Adajọ Dipẹolu ṣe sọ.

Adajọ Dipẹolu ṣalaye pe itusilẹ toun fun awọn ẹlẹwọn naa wa ni ibamu pẹlu ẹtọ, nitori wọn ko le wa ninu ẹwọn fungba pipẹ bẹẹ lai foju bale-ẹjọ.

O fi kun un pe DPP, iyẹn Director Of Public Prosecution to yẹ ko maa fun kootu nimọran to yẹ lori igbẹjọ ko ṣe bẹẹ fawọn ẹlẹwọn yii.

Nibi tọrọ ọhun buru de, Adajọ agba fidi ẹ mulẹ pe ẹjọ tẹlomi-in tori ẹ wa lẹwọn latọdun mẹjọ sẹyin ko ni faili kan ṣoṣo, ko si akọsilẹ ti wọn yoo fi to iwe rẹ, iru ẹni bẹẹ si wa lọgba ẹwọn lai jade.

Eyi lo n fa a ti awọn ọgba ẹwọn ṣe n kun akunfaya bi Adajọ Dipẹolu ṣe wi.

Nigba ti awọn eto bi eyi ba si ti n waye, o ni anfaani kan ni lati din ero ku lawọn ọgba ẹwọn to wa nipinlẹ Ogun.

Awọn ẹsun bii igbimọpọ-ṣiṣẹ ibi, idigunjale,igbinyaju lati paayan,ijinigbe,ifipabanilopọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni awọn ti wọn gba idande yii lufin ẹ ti wọn fi dẹni ahamọ,nigba ti ori si ti ba wọn ṣe ti wọn ti gba ominira yii, Adajọ agba gba wọn nimọran pe ki wọn dẹkun iwa to le da wọn pada sọgba ẹwọn ti wọn ti kuro.

O ni ki wọn jẹ ọmọluabi, nitori a ki i ri ẹfọn i ta lẹẹmeji, bi wọn ba tun fi bọ sọwọ ofin lẹẹkan si i,anfaani bii eyi ko ni i tọ si wọn mọ ladajọ agba wi.

 

 

ent from Yahoo Mail on Android

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here