Yóó ṣòro láti yí ìdàjọ́ náà padà nílé ẹjọ́ ọ kòtẹ́milọ́rùn

Yóó ṣòro láti yí ìdàjọ́ náà padà nílé ẹjọ́ ọ kòtẹ́milọ́rùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Agbẹjọ́rò àgbà nílẹ̀ yìí Amòfin Fẹ́mi Fálànà ti ní yóó ṣòro láti yí ìdàjọ́ náà padà nílé ẹjọ́ ọ kòtẹ́milọ́rùn.

Fálànà sọ pé “Ohun tó yẹ kí àwọn olùdìbò lágbègbè yẹn ṣe ni kí wọ́n pe INEC lẹ́jọ́ pé àjọ náà fi ìbò o wọn ṣòfò.”

Gẹ́gẹ́ bíi ohun tó sọ, yóó ṣòro fún àwọn agbẹjọ́rò Adeleke láti yí ìdájọ́ tó wà nílẹ̀ padà tí wọ́n bá dé ilé ẹjọ́ kọ̀tẹ́milọ́rùn.

Ó ní “Bí mo ṣe ń wo ìdájọ́ yìí, mo gbàgbọ́ pé yóó ṣòro láti yí ìdájọ́ náà padà.”

“Orí INEC ló yẹ kí wọ́n ti fọ́ àgbọn ohun tó ṣẹlẹ̀.”

“Ó yẹ kí INEC padà lọ tún èrò rẹ̀ pa kí irúfẹ́ nǹkan báyìí má baà wáyé mọ́.”

“Nítorí tí irúfẹ́ nǹkan báyìí bá wáyé nínú ètò ìdìbò Ààrẹ, ó lè dá rúgúdù tí apá INEC fúnra rẹ̀ kò ní-ín ká.”

Ẹ̀wẹ̀, Ademola Adeleke tí ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n gba ipò lọ́wọ́ ẹ̀ fún Oyetola ti sọ fún àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n má fa wàhálà kankan nítorí òun yóó gba ilé ẹjọ́ ọ kòtẹ́milọ́rùn lọ.

Àmọ ṣá, àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ kan ti ṣe ìfẹ̀hónúhàn nílùú Osogbo lópin ọ̀sẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here