Àníàní ko sí: Ìbò Òkè Ọya ni yóò sọ ẹni tí yóò di Ààrẹ   

    – Ìpínlẹ̀ Èkó le téńté lórí àtẹ àwọn tó forúkọ sílẹ̀, sùgbọ́n Òkè Ọya ni olùdìbò pọ̀ sí jù
   – Omilẹgbẹ èrò: Ganduje fi idán han Tinubu ní Kano
   – Atiku náà ń fakọyọ títí dé Anambra
   – Obasanjo, Clark kéde àtìlẹ́yìn fún Obi
   – Kwakwaso ń pòwe pé kannakáná p’ọmọ ẹ̀gà…
Gege bi atampako se maa n juwe okankan, ibo Oke Oya (North) ni yoo se atoka eni ti yoo bori idije ipo aare to n bo.
Idi ni pe Oke Oya ni awon oludibo po si julo.
Gege bi iroyin to jade lati odo ajo eleto idibo INEC, awon eniyan to foruko sile fun idibo je aadorun milionu ati meta o le die (93, 469,008).
Ninu eyi, milionu kan o din laadorin ni Oke Oya ko, bi o tile je pe Ipinle Eko lo ni oludibo julo laarin awon ipinle to ku.
Lapapo, ile Yoruba (South-West) ni bii milionu mejidinlogun (17,958,966).
Àníàní ko sí: Ìbò Òkè Ọya ni yóò sọ ẹni tí yóò di Ààrẹ   
Tinubu ni Knno
Niger-Delta (South-South) ni milionu meedogun o din die (14,440,714), nigba ti ile Igbo (South-East) ni milionu mewaa ati die (10,907,606).
O jo pe idi niyii ti oludije ipo Aare ni egbe All Progressives Congress, Asiwaju Bola Tinubu, fi n sise takuntakun ni Oke Oya.
Ko si abala orile ede yii ti ko maa kampee kaakiri, debi pe o sese lo si Enugu ni, to si se alaye ohun ti o fe gbe se fun opo awon oludibo.
Sugbon sa o, o mo ibi ti bota ti le de ori buredi re ju, ko si fi ibe sere.
Ti a b awa wo ibi ti Tinubu ti ri ero ju, Kano ni.
O ti n ri ero ni awon ipinle to ti n se kampee kaakiri, sugbon eyi to ba pade ni Kano se ara oto.
Obitibiti ero naa po de gongo debi pe okan oun ati awon olori egbe APC fee fo jade ni aya won nibi ti inu won dun de.
O tun je ohun iyanu pe awon opolopo egbe agbaboolu kaakiri Naijiria lo tun lo pade Tinubu lojo naa.
Eyi ko sele ri fun oludije ibo aare kankan.
Koda, bi Oloogbe MKO Abiola se gbayi to, to si nawo si ere idaraya, ti aye fi n pe e ni Pillar of Sports, awon egbe agbaboolu ko se bee fun ni 1993.
Sugbon sa o, iromi to n jo leti omi, onilu re wa ninu odo.
Eni to fi idan nla yii han Tinubu, to jo pe o seru ba awon oludije miran ni Gomina Ipinle Kano, Alagba Abdullahi Ganduje.
Ganduje wa lara awon to nigbagbo ninu Tinubu gidi.
O wa lara awon ti won jo pete ati-gbapoti naa.
Koda, oun ni won koko n so pe yoo se igbakeji, ki kinni naa to yi sori Kashim Shettima.
Sibesibe, Ganduje ko yese leyin Tinubu.
Lati ojo pipe, ibo Kano lo fee se pataki ju ni orile ede yii.
Ibe ni ibo to le ni milionu ti maa n yo gija, to si maa n gba awon alatako ni agbawole.
Ohun ti o tun se pataki ninu idije 2023 fun Tinubu ni pe awon gomina Oke Oya miran wa leyin re bi ike.
Lara won ni Gomina Ipinle Kaduna, Nasir el-Rufai ati Aminu Masari ti Katsina.
Ni ipinle mejeeji yii, obitibiti oludibo naa wa nibe.
Bakan naa ni awon gomina Borno, Kebbi, Zamfara ati Nasarawa.
Eyi lo maa n mu ki inu awon ololufe Tinubu ma ani i lokan pe nnkan yoo senu rere fun awon.
Oludije egbe Peoples Democratic Party, Alagba Atiku Abubakar; ti Labour Party, Peter Obi pelu New Nigerian People Party naa n pade oludibo kaakiri Naijiria.
Ero nla nla lo n pade Atiku naa, gege bi o se sele ni Anambra.
Ni ti Obi, o tun ti ri atileyin awon agbaagba bii Oloye Olusegun Obasanjo, Edwin Clark ati Afe Babalola.
Oludije kan ti awon amoye wa so pe ko see f’owo ro danu ni Rabiu Kwakwanso.
Oun naa ko  yee se akitiyan , ti igbagbo si wa pe o seese ko gba ipo keta.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here