Mo ṣetán láti sin àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fún sáà kejì báyìí – Oyetola

Mo ṣetán láti sin àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fún sáà kejì báyìí – Oyetola

Fẹ́mi Akínṣọlá

Lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ pé gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà Gboyega Oyetola ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje ọdún 2022, Gboyega Oyetola ti bá àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà sọ̀rọ̀.

Oyetola nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ilé rẹ̀ tó wà ní Iragbiji ní oríire náà kì í ṣe fún òun nìkan bíkòṣe fún gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ APC.

Ó ní ó jẹ́ ìmúgbòòrò ètò ìṣèjọba àwaarawa láti fìdí i rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni òun jáwé olúborí ètò ìdìbò tó kọjá.

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC fún àdúrótì wọn lásìkò tí gbogbo ìgbẹ́jọ́ náà fi wáyé àti pé ayọ̀ wọn ni bí ìgbìmọ̀ Tribunal ṣe dá ògo àwọn padà.

Bákan náà ló rọ̀ wọ́n láti ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí wọ́n má bàá ẹnikẹ́ni fa wàhálà tàbí hùwà jàgídíjàgan lórí ìdájọ́ náà.

Oyetola tún yin àwọn agbẹjọ́rò tó ṣiṣẹ́ fun lákin fún ipa ribiribi tí wan kó láti lè jẹ́ kí ọjọ́ òní wá sí ìmúṣẹ.

Ó tẹ̀síwájú pé ìdájọ́ yìí yóò jẹ́ ìwúrí fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn láti gbájúmọ́ ètò ìdìbò gbogbogboò tó ń bọ̀ lọ́nà láti fi gbé gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn wọlé.

Ó fi kún-un pé inú òun dùn gidigidi sí ìdájọ́ náà tí òun sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ọjọ́ òní nítorí ó bá òun ní òjijì.

Oyetola ní òun ti ṣetán láti sin gbogbo àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun fún sáà kejì báyìí àti pé ó dá òun lójú pé òun ni òun gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò tó wáyé ọ̀hún.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here