Ọ̀wọ́n èpo àti Náírà tuntun ni wọ́n fẹ́ fi dènà ìbò 2023 – Tinubu
Ọrẹ Òtítọ́jù
Àwọn àgbà ní bá á gúnyán, bá á rokà, ibi ẹ̀sun iṣu la ti í mọ̀.
Olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti pariwo síta pé gbogbo ìgbésẹ̀ tí ìjọba Orílẹ̀ yìí n gbé ni láti dabarú ètò ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2023 tí a wà yìí.
Oludije naa tii se ọmọ ẹgbẹ oselu kannaa pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari to n se ijọba lọwọ ni Naijiria wa salaye pe owo Naira tuntun ati ọwọngogo epo bẹntiroolu to wa nita lasiko yii ni wọn fẹ ẹ lo.
Tinubu lo sọrọ naa sita lasiko eto ipolongo idibo to ṣe niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, l’Ọjọru, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023.
Ipolongo idibo naa to waye ni Papa Iṣere MKO Abiola to wa lagbegbe Kutọ niluu Abẹokuta, lo kun fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri ipinlẹ Ogun, to fi mọ awọn ololufẹ agba oloṣelu naa.
Asiwaju ni Naira tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe jade ko si nita f’awọn araalu lati na, bẹẹ si ni awọn araalu tun n jiya fun epo bẹntiroolu.
O ni ijọba apapọ ṣe bi ẹni pe wọn ko mọ ohun to n lọ nipa awọn ipenija mejeeji yii, nitori pe gbogbo ipinnu wọn ni lati dabaru eto idibo apapọ.
Amọ Tinubu wa fọwọ sọya pe ohun to da oun loju ni pe awọn ọmọ Naijiria ko nii gba, wọn yoo jade lati dibo lọpọ yanturu, nitori pe ayipada rere ni wọn n fẹ.
“Wọn ko fẹ ki idibo yii waye. Wọn fẹẹ dabaru ẹ ni. N jẹ ẹ maa gba wọn laaye bii?
Wọn ti bẹrẹ sii gbe ọrọ aisi epo rọbii dide. Ẹ ma mikan, ti ko ba si epo bẹntiroolu, a maa fi ẹsẹ wa rin lọ sibi ti a ti maa dibo, a si maa dibo wa.”