Èyí nìdí tí Ọ̀ṣínbàjò, Ngige àtàwọn kan kò fi polongo ìbò fún Tinubu – APC

Èyí nìdí tí Ọ̀ṣínbàjò, Ngige àtàwọn kan kò fi polongo ìbò fún Tinubu – APC

Ọ̀rẹ Òtítọ́jù

Bí ó bá nídìí, obìnrin kì í jẹ́ Kúmólú. Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), ti ṣàlàyé ìdí tí lára àwọn èèkàn léèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú náà bí i Igbákejì Ààrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Ọ̀ṣínbàjò, Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ àti ètò ìgbanisíṣẹ́, Dókítà Chris Ngige, Mínísítà tẹ́lẹ̀rí fún ìgbòkègbodò ọkọ̀ àti ìrìnà, Rotimi Amaechi, kò fi kópa nínú ètò ìpolongo ìbó fún Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Aṣíwájú Bọla Ahmed Tinubu, wọ́n ní kì í ṣe tìjà, ọ̀rọ̀ náà ní bó ṣe jẹ́ ni.

Adari eto iroyin ninu igbimọ ipolongo ibo funpo aarẹ wọn, Amofin agba Festus Keyamọ, lo tanmọlẹ sọrọ naa lọjọ Ẹti, ogunjọ oṣu Kin-in-ni yii, o ni aṣẹ ti ọga Ọṣinbajo, iyẹn Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, pa fun un pe ko gbaju mọ ọrọ iṣakoso lasiko yii, tori iwọnba oṣu perete lo ku fun saa ọdun mẹjọ wọn, aṣẹ ọhun ni ko jẹ kawọn eeyan ri Ọṣinbajo bo ṣe yẹ nibi eto ipolongo ibo APC. Ni ti Igbakeji aarẹ, aṣẹ ti wọn pa fun un ni pe ko doju kọ iṣejọba. Tẹyin naa ba si kiye si i, Aarẹ ti n tẹle wa lọ sawọn ibi ta a ti ṣepolongo ibo.

 

O ni: “Rotimi Amaechi, iyẹn gomina ipinlẹ Rivers nigba kan, wa si eto ipolongo ibo ta a ṣe ni Adamawa ati Jos laipẹ yii, o ti bẹrẹ si i lọ sawọn rali (rally) wa kaakiri, ṣugbọn eyi to ba wu u lati lọ lo maa n lọ, ipinnu ara-ẹni ni.

“Bakan naa, Ngige, iyẹn Chris, to jẹ gomina ipinlẹ Anambra nigba kan, ko sọrọ ta ko ẹgbẹ wa, o kan jẹ pe o ti sọ p’oun ko ni i sọpọọti ẹgbẹ kankan, tabi oludije funpo aarẹ kankan ni toun ni, o loun fẹẹ duro ni danfo gedegbe, oun lo si mọ idi to fi ṣe ipinnu bẹẹ. Amọ ẹnikan ṣoṣo niyẹn jẹ laarin minisita bii mẹtalelogoji ta a ni.”

O waa kadii ọrọ rẹ pe: “Ko si ani-ani nibẹ, iṣọkan ati ajọṣepọ ẹgbẹ APC wa duro digbi ni, ko da bii ti ẹgbẹ PDP ti wọn ti fẹrẹ wogba tan.”

Tẹ o ba gbagbe, lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn eeyan ti n ṣakiyesi pe ẹkọ o ṣoju mimu laarin ẹgbẹ oṣelu APC, pẹlu bawọn agbaagba kan to yẹ ki wọn ṣugbaa oludije funpo aarẹ ẹgbẹ naa, Bọla Tinubu, ṣe n mọ eto ipolongo ibo rẹ loju tẹki. Lara wọn ni Ọṣinbajo, bẹẹ gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ọkunrin naa n jade lọ sawọn ode ayẹyẹ ati ariya mi-in bii ayẹyẹ ọgọrun-un ọdun ti wọn ti da ileewe Baptist Boys High School, Abeokuta, silẹ, eyi ti Ọṣinbajo pesẹ si, to si kopa to jọju nibẹ.

Wọn loju ti ẹgbẹ APC fi gunyan eto ipolongo rẹ kọ lo fi n gbọbẹ lọdọ awọn eekan eekan ẹgbẹ naa lasiko yii, amọ Keyamo ti ni didun lọsan yoo so fawọn nigbẹyin o.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here