Ìpínlẹ̀ Èkó yóò gbàlejò Ààrẹ Buhari –Sanwo-Olu

Ìpínlẹ̀ Èkó yóò gbàlejò Ààrẹ Buhari –Sanwo-Olu

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti kéde pé Ìpínlẹ̀ ọ̀hún yóó gba àlejò Ààrẹ Muhammadu Buhari fún ọjọ́ méjì ní ọ̀sẹ̀ yìí.

Kọmisọna feto iroyin ni ipinlẹ Eko Ọgbẹni Gbenga Omotoso, kede eyi lasiko apero kan ti o waye ni Alausa, Ikeja.

Omotoso ṣalaye pe abẹwo aarẹ ti yoo waye laaarin lọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun ati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni oṣu ọdun yii jẹ eyi ti Aarẹ yoo ti ṣe ifilọlẹ awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba Sanwo-Olu ti n ṣe paapaa julọ akanṣe iṣẹ ni ibudo okun Lekki Deep Sea, ile iṣẹ ti wọn ti n fọ irẹsi ni Imot ati akanṣe iṣẹ Reluwe ti ijọba ipinlẹ Eko ṣe.

Kọmisọna fi kun pe Buhari yoo tun ṣe ifilọlẹ iṣẹ akanṣe aladani kan ni Apapa ati pe gomina ati iyawo rẹ, Dokita Ibijoke Sanwo-Olu ni yoo ṣiwaju awọn ti yoo ki Aarẹ kabo.

Ijọba ipinlẹ Eko tun ti kede pe awọn opopona kọọkan ninu ìgboro Eko ati Lagos Island yoo wa ni titipa ni fun awọn ọjọ mejeeji ti Aarẹ Buhari yoo fi maa ṣe awọn iṣẹ yii.

Ni ọjọ aje, ko ni si eto irinna lagbegbe ilẹ iṣẹ to n fọ iresi ni Imota Ikorodu(Lagos Rice Mill)ati agbegbe Ibudo Okun Lekki Deep Port.

Bakan naa ni ọjọ keji ko ni si aaye fun lilọ bibọ ọkọ lagbegbe ile ìtura Eko Hotels ni opopona Ahmadu Bello, J-Randle lọ si Broad street ati Marina lati aago mẹfa aarọ si aago mẹta ọsan.

Frederic Oladeinde ni awọn awako ko ni le gba Opona Ahmadu Bello,Ademola Adetokunbo, ati Akin Adesola si afara Falomo kí wọn si gba opopona Alfred Rewane lọ si ibikíbi tí wọn ba n lọ.

Ẹwẹ, Kọmisọna naa ṣalaye awọn opopona miiran ti awọn awakọ le gba lojuna ati le din sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ku.

Awọn awakọ le dari si Onikan lati opopona Ozumba Mbadiwe ati Bonny Camp gba ori Afara Falomo tabi opopona Awolowo.

Bakan naa ni awọn awakọ lati opopona Awolowo lọ si Onikan, si Tinubu Square tabi awọn agbegbe to yi inu Eko ka le ko oju ọna Falomo lati jade si Alfred Rewane.

Fun awọn awakọ lati opopona King George V, ki wọn gba opopona Moloney si Obalende tabi ki wọn gba opopona Turton lọ si Moloney si Opopona Sandgrouse.

Fun awọn to n bọ lati Eko Bridge lọ si Marina kí wọn gba Elegbata si Ebute ero lọ si police post lati gun afara 3rd Mainland (Adeniji Adele) lọ si ibikíbi tí wọn ń lọ.

Frederic fi kun pe gbogbo opopona to dari si awọn ọna ti aarẹ Buhari yoo gba kọja ni yoo wa ni titipa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here