Fathia Balogun, Yọ̀mí Fabiyi, Kẹ́mi Afolábí àtàwọn èèkàn òṣèré míì kẹ́dùn ikú ‘Sir Kay’

Fathia Balogun, Yọ̀mí Fabiyi, Kẹ́mi Afolábí àtàwọn èèkàn òṣèré míì kẹ́dùn ikú ‘Sir Kay’

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀pọ̀ èèkàn òṣèré ni wọ́n ti n dárò gbajúmọ̀ òṣèré, Alhaji Kamal Adebayo, ‘Sir Kay’ tó jáde láyé.

Alhaji Kamal Adebayo, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí ‘Sir Kay Warrior’ jáde láye lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2022.
Fathia Balogun nínú ọ̀rọ̀ ìdárò tirẹ̀ fi àwòrán aṣàfihàn (emoji) ẹkún sí ojú òpó rẹ̀ pẹ̀lú àwòràn àbẹ́là tó n jò nínú òkùnkùn.

Ó wá kọ àkọlé “Irú ayé wo lèyí. Sir Kay…Ọlọ́run” sií orí àbẹ́là náà.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkẹ́dùn tí òun pẹ̀lú kọ sí orí ayélujára, Kẹmi Afọlabi ní “Hàà, rárá o. kò yẹ kó jẹ́ sir kay”

Bákan náà ni èèkàn òṣèrè, Jide Kosọkọ pẹ̀lú kẹ́dùn ikú òṣèrè tíátà náà pẹ̀lú.

Àdúrà pé kí Allah tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere, “Hùn kí Allah fún ní Aljanna.” ni Kòsọ́kọ́ kọ ní ti ẹ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ ìkẹ́dùn tí òun kọ sí ojú òpó Sítágíràmù rẹ̀, gbajúmọ̀ òṣèré àti olóòtù eré sinimá, Yọmi Fabiyi ní

“Ó dì gbà kan ná, Sir K Warrior. Wabili Kabbar. Sùnre o, akọni Ọkùnrin.”

Bákan náà ló tún kọ ọ́ sí àkọlé mìíràn pé ikú ‘akọni!’ náà, tó pè ní “Ẹ̀gbọ́n” mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here