Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ Ọ̀yọ́, owó oṣù kẹtàlá yín dájú, ẹ má dá àwọn alátakò lóhùn– Mákindé

Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ Ọ̀yọ́, owó oṣù kẹtàlá yín dájú, ẹ má dá àwọn alátakò lóhùn– Mákindé

Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní kúuṣẹ́, ní-ín mórí oníṣẹ́ yá, bẹ́ ẹ̀ èèyàn tó bá mọyì wúrà là á tà á fún.Ní báyìí,Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sèyí Mákindé ti kéde pé kí àwọn òsìsẹ̀ ìpínlẹ̀ ọ̀hún lọ fi ọkàn wọn balẹ̀ nítorí òun yóó san owó osù kẹtàlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe má a ń ṣe lọ́dọdún.

Gómìnà sọ eléyìí ni níbi ayẹyẹ ‘Christmas Carol’ tó wáyé nílé ìjọba ní Agodi nílùú Ìbàdàn, ó ní kí osù kejìlá tó parí ni òun ó ríi pé àwọn òsìsẹ́ gba owó ọ̀yà a wọn.

Ó wá rọ àwọn òṣìsẹ́ láti yàgò fún onírúurú ète tí àwọn ẹgbẹ́ alátakò ń gbé kiri láti ba ètò ìṣèjọba rẹ̀ jẹ́.

Gómìná tẹ̀síwájú pé gbogbo ọ̀nà làwọn alátakò òun ń ṣe láti ba ìṣèjọba òun jẹ́ pé òun kò ní àṣeyorí kankan sùgbọ́n ìbàjẹ́ ẹ wọn kò dá òun dúró láti san owó oṣù àwọn òsìsẹ́ kó tó di ìparí ọdún

Ó ní àwọn òsìsẹ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóó ni àǹfàní láti gba owó oṣù kẹtàlá mìíràn nítorí ìjọba òun kò fì gbà kan kọ iyán an wọn kéré rárá

“Ẹ má dáwọn lóhùn, a mọ̀ pé wọn yóó sọ pé bí mo ṣe fún-un yín lówó oṣù kẹtàlá lọ́dọọdún kì í ṣe àṣeyorí sùgbọn mo tún sọ fún-un p yín pé , kí oṣù tó parí, ẹ ó gba owó oṣù náà.

“Owó oṣù kejìlá àti ìkẹtàlá ni a san fún àwọn òsìsẹ́ ẹ wa láti fi ṣe ọdún kérésìmesì àti ayẹyẹ ọdún tuntun.

“Tí àwọn ẹgbẹ́ alátakò bá ní nǹkan mìíràn tó dáa ju nǹkan tí a ti ṣe ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ, kí wọ́n bọ́ síta láti sọ fún àwọn aráàlú ”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here