Òkò rùgùdù lórí Portable torí Small Doctor, àwọn ọ̀dọ́ Agége kọjú oro sí i lóde ijó

Òkò rùgùdù lórí Portable torí Small Doctor, àwọn ọ̀dọ́ Agége kọjú oro sí i lóde ijó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní ọ̀rọ̀ rere ní-ín yobì lápò, bẹ́ ẹ̀, ọ̀rọ̀ burúkú ní-ín yọfà nínú apó, bẹ́ ẹ̀ lọ̀rọ̀dà o fún gbajúmọ̀ olórin tàkansúfèé n nì, Habeb Okikiola, ẹni tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Portable Ọmọ Olalomi bó ti kan ìjàngbọ̀n lóde ijó.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà tí àwọn olólùfẹ́ olórin Small Doctor ń sọ ike omi lù ú lákòókò tó fẹ́ kọrin níbi ìpàtẹ orin tó wáyé ní agbègbè Agége nílùú Èkó.

Saájú ni Portable ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí Small Doctor lórí ẹ̀rọ ayélujára àmọ́ tí ọkùnrin kan, Abul Abel ti báwọn pẹ̀tù sí aáwọ̀ ọ̀hún.

Nínú fídíò nípa ohun tó fa ìjà láàrin àwọn olórin méjéèjì, èyí tó ti gba orí ayélujára kan báyìí, ni Portable ti fi ẹ̀sùn ìwà ọ̀dàlẹ̀ kan Small Doctor.

Portable ní Small Doctor kéré sí nọ́ńbà òun nínú àwọn olórin tí ó jáde láti inú Agége.

Nígbà tí Small Doctor ń fi Portable hàn láti wá kọrin, ṣe ni àwọn ọ̀dọ́ agbègbè Agége bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ike omi mọ́ ọ, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́ ohùn orin fu rẹ̀ láàrin wọn.

À mọ́ kàkà kí Portable bẹ̀bẹ̀, kó sì pẹ̀tù sáwọn èrò ìwòran ọ̀hún nínú, ṣe ló ń fapá jánú, tó sì ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí wọn.

Ìdààmú Àdúgbò ń pariwo pé àwọn èrò ìwòran ọ̀hún tó fi owó wọlé síbi ètò orin ‘Àwọn ló fi owó wọn pe wàhálà”, èyí tó mú kí inú bí àwọn ọ̀dọ́ Agége.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onígbọ̀wọ́ ìpàtẹ ayẹyẹ ijó náà, Small Doctor, rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn òǹwòran náà, ṣùgbọ́n se ni àwọn ọ̀dọ́ ọ̀hún yarí, tí wọn kò sì fẹ́ rí ìgbẹ́ Portable láàtàn.

Ohun tó sì sokùnfà báwọn òǹwòran ọ̀hún se yarí kanlẹ̀ ni pé wọ́n ní Portable fi ẹ̀gbin rẹ́ Small Doctor lára, bẹ́ẹ̀ sì ni ọmọ agbeègbè Agége ni Small Doctor jẹ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here