Àwọn agbanipa pa olùdíje sípò aṣòfin ẹgbẹ́ Labour, wọ́n tún dáná sunlé e rẹ̀

Àwọn agbanipa pa olùdíje sípò aṣòfin ẹgbẹ́ Labour, wọ́n tún dáná sunlé e rẹ̀

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ní fẹ̀rẹ̀mọ́jú ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kejìlá, ọdún yìí, làwọn agbébọn kan tí wọ́n fura sí pé agbanipa ni wọ́n, ya lọ sílé Ọ̀gbẹ́ni Christopher Elehu, tí í ṣe olùdíje fúnpò aṣojú–ṣòfin tí yóó ṣojú Ìjọba ìbílẹ̀ Onuimo, ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún, láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, tì wọ́n sì dá ẹ̀mí ẹ̀ légbodò.

Lẹyin ti wọn pa a tan, ni wọn lawọn ẹni ibi yii tun dana sun ile ati dukia ẹ, titi kan ọkọ alupupu to wa layiika ile ẹ. Fun bii wakati meji leralera ni wọn lawọn afurasi ọhun fi n yinbọn nidaaji kutukutu, nigba tẹnikẹni o ti i ji bọ sita niluu naa.

A gbọ pe awọn to ṣiṣẹ buruku ọhun tun n ya ile awọn oloṣelu yooku laduugbo ọhun lẹyọ kọọkan ṣugbọn ori ba awọn yẹn ṣe e, wọn ko si nile lasiko akọlu naa.

Ọkan ninu awọn alatilẹyin ọkunrin naa ṣalaye pe “Wọn ti pa Christopher Elehu ti gbogbo awọn eeyan maa n pe ni Wasco o. Nigba aye ẹ, oun ni oludije funpo aṣofin kekere nijọba ibilẹ Onuimo. Nigba ti wọn ri i pe oorun ti wọ awọn eeyan lara ni wọn ya bo ile ẹ, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn fun bii wakati meji. Lẹyin ti wọn pa ọkunrin yii tan, bii pe eyi ko ti i to, niṣe ni wọn tun sọna sile ẹ ti wọn jo o kanlẹ. Gbogbo awọn nnkan-ini ẹ pata tọwọ wọn ba ni wọn bajẹ raurau. Nigba ti gbogbo abule fi maa de ibi ti oku ẹ sun gbalaja si, oju ada ati aake to wa lara ẹ ko ṣeeka”.

Haa-hin-in lọrọ iku ọkunrin naa n ṣe gbogbo awọn eeyan abule wọn, awọn ti ki i ṣe oloṣelu laarin wọn gan-an si n bẹru, nitori boya lo le ti i ju ọjọ mẹwaa lọ lẹyin ti oludije lẹgbẹ oṣelu Labour Party nijọba ibilẹ mi-in to sun mọ wọn, Ọgbẹni Chukwunonye Irouno, ku lojiji.

Irouno yii ti wọn yan gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣakoso eto ipolongo aarẹ ẹgbẹ Labour nipinlẹ naa, lo ṣadeede ṣubu lalẹ ọjọ ipolongo ibo ku ọla. Bo tilẹ jẹ pe wọn sare gbe e digbadigba lọ sile iwosan ijọba apapọ Federal Medical Centre, niluu Owerri, ni kete ti wọn gbe e debẹ lawọn dokita sọ pe ọkunrin naa ti dagbere faye.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here