Ọjọ́ tí Sanwo-Olu pa Iya Awero lẹ́kún ayọ

Babajide Sanwo-Olu ati Iya Awero

Bi o ti le je pe ogbologbo onitiata, Lanre Hassan, ti gbogbo eniyan mo si Iya Awero, ti sun ekun eke ninu opolopo fiimu, Gomina Ipinle Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti mu ki o sun ekun ooto ni ojo naa.

Sugbon ekun ayo ni, ekun imoore si ni pelu nitori pe gomina naa ya a lenu pelu fifun ni ebun ile.

Nigba ti o n soro ninu iforowero kan leyin ojo die ti won fun ni kokoro ile naa ti o wa ni Ikorodu, Iya Awero wi pe oun ko le e da imolora oun duro nitori pe o je imoore fun gbogbo ojo aye eni.

Osere naa ni, “O de ba mi bi ohun iyalenu. Mi o rokan debe rara. Inu mi si dun si i. Mi o le da ara mi duro, n ko tile mo igba ti omije bo loju mi.

“Mo dupe pupo lowo ijoba ipinle Eko. Gomina Babajide Sanwo-Olu so pe ko digba ti a ba ku ki won to mo riri wa, iyen si se pataki. Bi won ba mo riri eniyan nigba aye re, eniyan a mo pe oun n se daadaa, eniyan yoo si gbiyanju lati se daadaa si. Ni ona naa, awon iran ti o n bo leyin ni yoo je ohun iwuri fun lati sa ipa won nitori ti won mo pe aye yoo mo riri won.

“Awa(osere) n mu ki awon eniyan rerin ti won yoo fi gbagbe ibanuje won, o si je ohun ti o dara bi won ba mo riri wa. Awon toku gbodo keeko lati ara ohun ti ijoba ipinle Eko se.

“O wa ni akoko ti o dara nitori pe mo si wa laaye. Igbakugba ti Olorun ba bukun eniyan, o ye ki eniyan gba tokantokan. Ko si owo pupo ninu ere sise. Sibesibe, ise wa wa pelu opolopo iyi ati eye. Gbogbo ibi ti a ba lo ni won ti n mo riri wa.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here