Igwe ati Tinubu

Mary Seunfunmi Fagbohun

Ilumooka onitiata ati agbere jade, Ebun Oloyede, ti gbogbo eniyan mo si Olaiya Igwe, ti so pe oun moomo se igbasile akanse eto adura ti oUN se ni ihoho omoluabi ninu odo kan fun oludije ipo aare ninu egbe oselu All Progressives Congress, Asiwaju Bola Tinubu.

Olaiya ti da  awuyewuye sile ni bi awon kan se fi oju tembelu wo o fun jijaso lara lati se eto naa.

Sugbon o wi pe, ipinnu naa je ti oun, ti oun ko si kabamo re.

Osere naa ni, “Laarin awon Yoruba, Babalawo a maa wi fun ni pe bi o ba fe se iwure, gbe ebo tabi se etutu, lo si aarin oja tabi gbagede kan. Eleyii niise pelu oun ti mo se. Mo moomo se igbasile eto naa fun awon eniyan lati ri. Mo moomo se, mi o si kabamo re. Onikaluku ni o ni iyato re. Niwon igba ti ohun ti mo n se ko le e pa enikeni lara.

“Asiwaju Bola Ahmed Tinubu je eja nla ninu aye mi, mo si mo pe yoo di aare orile ede Naijiria laipe. Mo le e se ohunkohun fun Asiwaju.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here