Àwọn ajínigbé ń bèèrè owó tuntun láti tú ẹni tí wọ́n jígbé sílẹ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀rọ̀ burúkú tòun tẹ̀rín ni ọ̀rọ̀ ọ̀hún rí nígbà tí àwọn ajínigbé bèèrè lọ́wọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí ènìyàn tí wọ́n jí gbé wí pé owó tuntun tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ní àwọn ń fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó ìtúsílẹ̀.
Àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí agbéṣùmọ̀mí tó jí àwọn ènìyàn mẹ́rin gbé ní ìlú Kolo, ìjọba ìbílẹ̀ Gusau ní ìpínlẹ̀ Zamfara ló tún gba ọ̀nà mìíràn yọ báyìí.
Àwọn mẹ́rin tí àwọn afurasí náà jí gbé náà ni ọkùnrin kan, obìnrin kan àti àwọn ọmọdé méjì.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà ni àwọn ajínigbé náà kọ́kọ́ bèèrè fún gẹ́gẹ́ bí owó láti tú àwọn ènìyàn náà sílẹ̀.
Àmọ́ nígbà tó yá ni àwọn ajínigbé ọ̀hún gbà láti gba mílíọ̀nù márùn-ún náírà láti tú àwọn ènìyàn náà sílẹ̀.
Ará ìlú náà kan tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ sọ wí pé bí àwọn ṣe ń sáré kiri láti wá owó náà láti ri wí pé àwọn gba ìtúsílẹ̀ àwọn ènìyàn náà ni àwọn ajínigbé ọ̀hún tún gba ọ̀nà mìíràn yọ.
Ó ní òwúrọ̀ òní ni àwọn ajínigbé náà tún fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí àwọn wí pé owó tuntun tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ní àwọn ń fẹ́ wí pé àwọn kò fẹ́ èyí tí à ń ná lọ́wọ́ báyìí.
Ó ṣàlàyé pé àwọn ajínigbé náà ní àwọn yóò fi àwọn ènìyàn tí àwọn jí gbé náà sí àhámọ́ àwọn títí ìjọba yóò fi kó owó tuntun jáde nínú oṣù Kejìlá.
Ìgbìyànjú láti gbọ́ látẹnu agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Zamfara, Mohammed Shehu lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ ló já sí pàbó.