Ojise Olorun Johnson Suleiman ti awon onise ibi kọ lu ni ana ọjọ Ẹti, ojo kokanlelogun, osu kewaa odun yii lo n forere pe, lati odun 2017 ni awon eniyan bururku yii ti n lepa ẹmi oun.
Apostle ni o yẹ ki oun darukọ awon onisẹ ibi naa, amọ o ku die nitori pe oun mọ daju pe won maa ko jalẹ peawon ko lepa emi ẹni Kankan. O ni isele ojo Jimo naa buru pupo nitori awon emi ti won ko le da ni won se lofo. Eniyan meje tan lo ba isele naa lo nigba ti won doju ibon kọ mọto oun ati awọn ti awon jọ n lọ.
Apostle jẹ ki o ye awon onise ibi naa pe “iku ati ọdọ Olorun nikan lo le mu oun lọ”. O ni oun si mo daju pe ẹlẹsẹ Kankan ko ni lo lai jiya. O ni gbogbo awon to n lepa emi oun ni asiri won maa tu faye laipe nitori pe oun ko mọ oun ti o n bi won ninu pelu ise Olorun ti oun gbe dani ti o si n te siwaju.
Apostle ni asiko oro ko tii to bayii nitori pe awon si n se idaro awon Olopaa merin pelu awon omo olomo meta to ba ajalu naa lo ni opopona Benin si Auchi.