Gege bi ajafeto omo Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo, ti opo mo si Sunday Igboho, se n gbaradi lati pada si Naijeria lati Cotounu, IROYIN OWURO ti seranti bi agba oje olorin emi, Timi Osikoya, se korun fun un nigba ti nnkan n gbona janjan.
Awon eniyan kan gba pe oloogun paraku ni Sunday Igboho.
Oun ni eni to n ja ija ajagbara fun Yoruba bayii, to si to koko wa ni ahamo ni Cutounu, nibi to ti ba ijoba jejo, latari bi o se fe te baalu leti lo si orile ede Germany.
Eyi waye leyin ti ijoba Naijiria kede lile e kiri gege bi odaran.
Sibesibe, olori emi to je gbajugbaja nigba kan, Alagba Timi Oshikoya, se orin kan fun un lati fi idunnu han lori ija ajagbara to n ja.
Akorin naa ti opo eniyana mo si Telemi so pe oun se eyi nitori ija ti Sunday Igboho n ja, kii se tori ti ara re nikan.
O ni o n ja ija naa lati gba awon eniyan re sile ni.
Telemi ni oun ko fara mo ohun kan ti awon eniyan kan n so pe oloogun ni Igboho, nigba ti oun je omolein Jesu.
O ni ti won ba ni oloogun ni Igboho, a ria won pasito kan naa ti won n lo oogun, ti won n ba Babalawo se awo.