Lasun Alagbe
Ni nnkan bii osu die seyin ni IROYIN OWURO ti koko woye oro yii.
A ri i bo se je pe kadara ati ayanmo se n rerin-in si gbajugbaja akorin Fuji, WQasiu Ayinde lojoojumo.
Lenu ise orin to yan laayo, laarin egbe ati ogba, ilosiwaju n ba a lodoodun ni.
A ranti bi Alaafin to waja, Oba Lamidi Adeyemi, se fi je oye Mayegun ti ile Yoruba.
Lojo die seyin naa, o mo tun di eni ti Aare Muhammadu n foye orile-ede yii da lola.
Eyi je ka wo o nigba naa pe loooto, eni ti Olorun ba da, ko see fi ara we.
Gege bee ni ti akorin fuji to je gbaju-gabaja, Wasiu Ayinde, ri.
Bi igba se n yi to, bi awuyewuye se n waye ni sakaani re leekookan to, Olorun si n fun un ni ise fuji se.
Apere eyi tun n waye ti a ba wo bi awo orin to gbe jade laipe ni nnkan bii odun meji seyin, to si n se daadaa loja.
Abi ibo ni won ko ti maa gbo Ade Ori Okin tit di oni?
Orin yii ni o n je ki opo eniyan maa dófun tolo nibi sise, ti won sim aa n so idi wuke bi o ba tin lo.
Awo orin naa lo je eyi ti awon orin ti Wasiu ti ko tele po ninu re.
Sibesibe, awon araye tun n ko o je ni.
Ohun ti eyi tumo si ni pe, lati odun 1984 ti Wasiu ti lagboro ja pelu ‘Tala ‘84’, gboin ni toóke ni oro re ja si.
Ni bayii, o ti le ni omo ogota odun daadaa, sibesibe tomode-tagba lo n gbo orin re.
Gege bi IROYIN OWURO se woye, ailara pupo re, ebun to ni to fi maa n so orin di tuntun, ati ni pato, kadara, tii je ebun Olodumare lo so o di iroko nla ti eni kan ko le wo lule.