Awuyewuye PDP: Yanmuyanmu Wike ba le Atiku ni tibi, oro di suuru

Wike ati Atiku

 

Awuyewuye to n lo ninu egbe oselu Peoples Democratic Party lori bi Alaga won, Iyorchia Ayu, se tun wa nipo ko tii ro o.

Gomina Ipinle Rivers, Nyesom Wike, lo ko awon olori egbe naa miran kan sodi, ti won ni Ayu gbodo fi ipo naa sile.

Idi ni pe Oke Oya (North) NI Ayu ti wa, to si je pe ibe naa ni oludije ipo Aare won, Alhaji Atiku Abubakar, ti wa.

Wike wa n wo o pe eyi ko ba ofin egbe naa mu – ki oludije aare ati alaga wa lati abala ibi kan naa, ki awon Odo Oya ma w ani oju Kankan nibe.

O fi kun un pe o ya oun lenu pe adari eto ipolongo ibo fun Atiku, Oke Oya ni oun naa ti wa.

Lara awon ti won wa po pelu Wike lori oro yii ni Gomina Ipinle Oyo, Alagba Seyi Makinde; Oloye Bode George, Gomina Ekiti ana, Ayodele Fayose; ati Ojogbon Jerry Gana.

Atiku ko so pe oun ko oro Wike danu; sugbon o ni oun ko le deede yo Ayu, tori ofin naa lo gbe e depo.

O ni bi won tile yo o naa, ofin ni ki igbakeji re bo si ipo naa ni.

Bee, Oke Oya ani oun naa ti wa.

O wa jo pe oro naa so s I lenu, o wa buyo si i.

Sibesibe, Wike si n ke fatafata ni pe oun ko ni gba, oun ko ni gbo.

O jo pe Atiku ti gba kamu pe ko se oun to ba fe se, sugbon ko so bee sita.

O kan so pe Ayu nikan lo le funra re fiwe sile ni.

Bi ojo ibo se n bo lona, to si je pe Atiku ko ni fe padanu ibo Rivers, oro naa wa da bii yamuyamu to ba leni lepon: afi keeyan fi suuru pa a.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here