Eni to ni kin laa se laa se e fun: Sanwo-Olu fakoyo ni Ipinle Eko

Sanwo-Olu

Akeem Lasisi

–        Oko oju irin reluwee fe bere

–        O n ko opo ile iwe

–        Ilegbee awon akekoo n bo ni LASU

–        Osibitu awon omode Messey di atunko

–        O se ribiribi lori ona ati ise agbe abbl

 

Ti won ba n pa owe pe eni ti o ni kin laa se, oun laa se e han, o jo pe Gomina Ipinle Eko, Alagba Babajide Sanwo-Olu, ni won n so nipa re.

Awon eniyan kan ti ko mo ipa ati ebun to ni, pelu emi isinlu, se gbenugbenu nigba ti o sese n gbe apoti ibo.

Awon kan tie ni olori egbe All Progressives Congress ati oludije ipo aare, Asiwaju Bola Tinubu, kan fe fi Sanwo-Olu di gereu ni.

Sugbon leyin odun meta o le die ti gomina naa ti dori aleefa, lala ti lu, aruputu ti hu.

Gege bii eni to ni kin laa se, o ti se e han won.

Yala lori eto eko ni, eto irinna, eto ilera, eto oro aje ati iseranwo fun awon alaini, Sanwo-Olu ti n sanjo fun awon oludibo.

Nigba ti o koko gori aleefa, idoti wa kaakiri Ipinle Eko, ti gbogbo titi n run rai.

Bakan naa, opolopo ona aarin ilu lo ti baje.

Bee, opo awon ile iwe ni won n sunkun atunse.

Bi o tile je pe awon gomina to ti je ki oun to depo, bii Akinwunmi Ambode, Babatunde Fashola ati Tinubu funra re, gbiyanju to won, ti won si gboriyin lopolopo, nnkan ko senu rere lori awon nnkan ti a la sile yii.

Eyi fa a ti ariwo ati awuyewuye fi po ni awon osu akoko ti Sanwo-Olu fi wa nipo.

Sugbon, ni werewere, ni sise-n-tele, Sanwo-Olu ti mu ki opo awon isoro Eko di afiseyin ti eegun n fiso.

Lona kinni, idoti gelete gelete ti poora ni Eko.

Lona keji, opo ona to baje nigba naa ni won ti tun se, to si je pe owo ko duro rara lori won.

Ti a ko ba gbagbe, orisiirisii awon agbasese ni Sanwo-Olu gbe awon ona naa fun.

Bi won si se n sise lojooumo ni Komisanna Eto Iroyin ati Ilana, Alagba Gbenga Omotoso, maa n se atejade bi won se nsise lori awon ona naa lojoojumo.

Ko tan sibe o. Ijoba Sanwo-Olu ti fe so ala ki Eko ni reluwee di amuse bayii.

Oloogbe Lateef Jakande lo koko gbiyanju oko oju irin fun Ipinle naa.

Sugbon ijoba Ologun da iyanju naa nu ni odun 1984.

Igba ti awon gomina Fashola ati Ambode de ni won bere ise nla naa pada.

Sanwo-Olu de, o fe e loju, o si ri pe ise ko duro lori re.

Messey Hospital ti Sanwo-Olu n ko

Lara awon aseyori pataki ti o tun ti se ni atunko awon ile iwosan, paapaa ile owosan awon omode Messey Hospital, eyi to wa ni agbegbe Adeniji Adele tele.

O n se iwosan ofe kaakiri osibitu fun awon omode si omo odun mejidinlogun, at awon agbalagba ti won ti pe odun marundinlaadorin.

Lati igba ti won ti da ile eko giga Lagos State University, eyi to wa ni Ojo, sile, ko ni ilegbee awon akekoo ti a n pe ni hostel.

Bayii, Sanwo-Olu tib ere si ko olopo yara fun won.

Bakan naa ni  o n ko awon ile iwe alakobere ati sekondiri kaakiri ipinle naa.

Sanwo-Olu ti ko ile gbigbe estates to ti le ni egberun meta.

Pelu  awon ise ribiribi yii, opo eniyan lo gba pe atipada sipo re ni 2023, bi eni n feran jeko ni.

Ohun to tun maa se iranwo fun un ni bi o se n seto iselu ni ilana to to n ko gbogbo eniyan mora.

Awon oloselu ko ni wahala  kan pelu re, bee awon onise okowo, awon onimoto, iyaloja ati elere idaraya wa pelu re.

Bi ako ba gbagbe, ijoba Sanwo-Olu tib ere sii ya awon onifiimu lowo, ki idagabsoke tun le ma bai se won/

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here