Tinubu gbé ìpèníjà Nigeria lọ ilẹ̀ mímọ́ ní Saudi

Tinubu gbé ìpèníjà Nigeria lọ ilẹ̀ mímọ́ ní Saudi

Múdàsírù Àlàbí

Aarẹ orileede Nigeria, Asiwaju Bola Ahmmed Tinubu ti gbe awọn ipenija ilẹ yii lọ si ilẹ mimọ.

O se adura pẹlu awọn ẹni Ọlọrun, o sọ gbogbo ẹdun ọkan rẹ f’Ọlọrun.

Tinubu gbadura ni Umrah naa pe ki Ọlọrun jọwọ jẹ ki ifẹ, irẹpọ ati irọrun wa ni orileede yii. O ni ki Allah dakun ba wa fopin si awọn ajinigbe, agbenipa ati awọn ti ko fi orileede yii lọkan balẹ.

Grand Mosque ti ilu Makkah ni adura ọjọ Jimọ ti waye.

Diẹ ninu awọn to ba Aarẹ rin irinajo naa ni – AbdulRahman AbdulRazaq tii se gomina ipinlẹ Kwara, Uba Sani ti Kaduna, Mai Mala Buni ti Yobe, Babagana Zulu ti ipinlẹ Bornu, Umar Namadi ti Jigawa, Femi Gbajabiamila to jẹ Chief of Staff fun Aarẹ Tinubu naa lọ, Abdulaziz Yari ti ipinle ipinlẹ Zamfara, Wale Tinubu ti se olori ati alasẹ ile-epo Oando, Abdulsamad Rabiu ti oun naa n se alasẹ ati oludari BUA Group naa tẹle Aarẹ pẹlu awọn eniyan miiran.

Bayo Onanuga tii se agbani-nimọran labala iroyin lo fi eyi lede.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here