Inúnibíni kò lè mú ìlọsíwájú bá wa ní Nàìjíríà – Ọọ̀nirìṣà
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ọọni ti ile-ifẹ, ti rọ gbogbo awọn ọmọ Yoruba ati gbogbo ẹya to ku ni Naijiria lati wa ni irẹpọ ati iṣọkan ki orilẹ-ede Naijiria le dara. Ooni parọwa yii nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ to waye ni ilu Ile Ife, ipinlẹ Osun.
Ọba Ogunwusi woye pe, a ko le maa binu ara wa ki a maa wa ni ireti pe orilẹ-ede Naijiria maa goke agba tabi ki alaafia ko jọba nibẹ nigba to jẹ pe awọn eeyan naa lo n jẹ orilẹ ede.
O ni gbogbo igba ni awọn ẹlẹṣin Kristẹni, awọn Musulumi ati awọn Oniṣẹṣe maa n ke pe Olodumare fun ilọsiwaju orilẹ-ede Naijiria ṣugbọn to ni eyi ko le wa si imuṣẹ ti ko ba si ifẹ ati irẹpọ to dara laaarin gbogbo ọmọ Naijiria lai fi ẹsin tabi ẹya ṣe.
O wa rọ gbogbo ọmọ Naijiria maa lo ifẹ laaarin ara wọn, to si ohun nikan lo le ṣe iranwọ lati tun orilẹ-ede Naijiria ṣe.
Ọọni parọwa yii lasiko to wa ni igbele ọlọjọ meje to maa n ṣaaju aṣekagba Ọdun Ọlọjọ, ki wọn to gbe ade Are jade lati fi wure fun gbogbo ilu.
Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá, irinwó àti ẹyọ̀kan ni àwọn Òrìṣà tó wà ní Ile-Ife, ìpínlẹ̀ Osun àti pé gbogbo wọn ló ní ọjọ́ tí wọ́n máa ń bọ wọ́n.
Ọdún Ọlọ́jọ́ jẹ́ ọdún kan pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá èyí tí wọ́n fi máa ń ṣàmì ọjọ́ tí Olódùmarè dá ilé ayé.
Ọdún Ọlọ́jọ́ wà lára àwọn ọdún tó ti pẹ́ ní ilẹ̀ Yorùbá.









