Tinubu, Akpabio àti àwọn ọ̀tọ̀kùùlú rọ̀jò owó fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin U – 17
Mudasiru Alabi
Gbogbo ohun ti eniyan ba mọ ko saa maa se e daadaa, eyi lo difa fun bi Aare Bola Tinubu ati Godwin Akpabio pẹlu awọn ọtọkuulu se n rọjo owo fun awọn ọdọbinrin ti wọn jawe olubori nibi ife ẹyẹ agbaye.
Ọgọrun-un miliọnu naira ni Aarẹ seleri nigba ti olori ile-igbimọ asofin seleri iye kan naa. Bẹẹ si ni awọn gomina kọọkan ti n ransẹ pe wọn lati wa gbe ife ẹyẹ naa ki wọn.
Eyi naa si tun maa sọ wọn dolowo ati ọlọrọ.
Olùkọ́ni àgbà, Hakeem Busari, yóò gba ₦100 mílíọ̀nù ní owó gidi, nígbà tí ọmọ ẹgbẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀-ẹ̀rọ (technical crew) kọ̀ọ̀kan yóò gba ₦50 mílíọ̀nù.
Ẹgbẹ́ Flamingos f’ìtàn balẹ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, Oṣù kọkànlá ọjọ́ keje, lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹ́gun Japan 2-1 ní ìparí eré ní Rabat, ní Orílẹ̀-èdè Morocco, láti di ẹgbẹ́ àkọ́kọ́ ní Áfríkà tí yóò gba Idije Ife Ẹyẹ Agbaye ti U-17 ti awọn Obìnrin.









