JAMB 2026: Oloyede fajúro sí àwọn tó ní kí obìnrin kan yọ Hijab ní Ìbàdàn

JAMB 2026: Oloyede fajúro sí àwọn tó ní kí obìnrin kan yọ Hijab ní Ìbàdàn

Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí

Idanwo asewọle si Fasiti (JAMB) kaakiri orileede yii ti bẹrẹ lati ọjọ kẹrindinlogun, osu kẹrin ọdun yii gẹgẹ bii alaalẹ ajọ naa.
Idagbasoke tun ti de ba ajọ idanwo naa, bi wọn se n se idanwo ni esi rẹ n jade ni ọjọ keji. Eyi mu ki gbogbo ọmọ Naijiria maa Kan saara si ajọ naa.
Eyi to ya olori ajọ naa (Ọjọgbọn Ishaq Oloyede) lẹnu ju nibi idanwo naa ni ibusọ idanwo kan ti wọn ti ni ki arabinrin kan yọ Hijab to fi bori kuro.
Oloyede ni “Bawo ni wọn se maa ni ki iyawo oniyawo yọ ohun to fi bori, ẹ ba mi wa ipagọ naa ni ilu Ibadan?”
Oloyede ni eyi ko tọna rara, loju ẹsẹ lo si n beere ibi ti isẹlẹ naa ti sẹlẹ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here