Iyán ogún ọdún n jó Aregbesola lọ́wọ́ nípa Tinubu

Iyán ogún ọdún n jó Aregbesola lọ́wọ́ nípa Tinubu

Awọn ololufẹ ayelujara ti ya bo Ogbeni Rauf Aregbesola lori ayelujara. Ori ẹrọ ayelujara yii kan naa ni Aregbesola ti n salaye ilo ede ti ko dara ti Tinubu lo ni ilu Abeokuta pe “emi lo kan”.
Aregbesola ni ilo ede naa ko dara rara, o lọwọ igberaga ninu, o tun salaye siwaju sii bayii pe “O n salaye bi ẹni to ni agbara lati oke pe emi lo kan, ko sọ pe awa lo kan tabi ẹgbẹ lo kan tabi eeyan lo kan.”
Eyi lo mu ki awọn eniyan maa soko ọrọ sii pe ‘o yẹ ẹni gbogbo ko dinwo aro, ko yẹ atọọle.’ Wọn ni lẹyin ogun ọdun ti Tinubu ti n fẹyin pọn ọn bọ, o wa le maa sọọ jade bayii pe Tinubu ni ede igberaga lẹnu bii alagbara kan.
Wọn ni Tinubu to sọọ di kọmisọna fun ọdun mẹjọ, to sọọ di gomina f’ọdun mẹjọ, to sọọ di minisita f’ọdun mẹrin ni ko wa gbede mọ lẹyin ogun ọdun.
Onikaluku kan n sọrọ saka-saka si Aregbesola lori fọnrọn ti enikan lọ wu jade nipa rẹ nigba ti o naka aleebu si Tinubu nibi eto idibo to kọja.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here